AISAYA 27

27
1Ní ọjọ́ náà,#Job 41:1; O. Daf 74:14; 104:26
OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára,
pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò,
Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké,
yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun.
2Ní ọjọ́ náà,
OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé,
3“Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀,
lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín;
tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọ
kí ẹnìkan má baà bà á jẹ́.
4Inú kò bí mi,
ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀,
ǹ bá gbógun tì wọ́n,
ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀.
5Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò,
kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa;
kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.”
6Ní ọjọ́ iwájú
Jakọbu yóo ta gbòǹgbò,
Israẹli yóo tanná, yóo rúwé,
yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé.
7Ṣé OLUWA ti jẹ wọ́n níyà bí ó ti fìyà jẹ àwọn tí ó jẹ wọ́n níyà?
Ṣé ó ti pa wọ́n bí ó ti pa àwọn tí ó pa wọ́n?
8OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀,
ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn;
ó lé wọn jáde ní ìlú,
bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn.
9Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́,
tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé:
Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú,
bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná;
kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró.
10Nítorí ìlú olódi ti di ahoro,
ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù;
ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko,
wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀.
11Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dá
nígbà tí wọ́n bá gbẹ,
àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná.
Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá;
nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn,
Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn.
12Ní ọjọ́ náà,
OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà,
láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti,
yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan.
13Ní ọjọ́ náà,
a óo fun fèrè ogun ńlá,
àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria
ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti
yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 27: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀