LI ọjọ na li a o kọ orin yi ni ilẹ Juda; Awa ní ilu agbara; igbala li Ọlọrun yio yàn fun odi ati ãbo. Ẹ ṣi ilẹkun bodè silẹ, ki orilẹ-ède ododo ti nṣọ́ otitọ ba le wọ̀ ile. Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ. Ẹ gbẹkẹle Oluwa titi lai: nitori Oluwa Jehofa li apata aiyeraiye: Nitori o rẹ̀ awọn ti ngbe oke giga silẹ; ilu giga, o mu u wálẹ; o mu u wálẹ; ani si ilẹ; o mu u de inu ekuru. Ẹsẹ yio tẹ̀ ẹ mọlẹ, ani ẹsẹ awọn talaka, ati ìṣísẹ̀ awọn alaini. Ọ̀na awọn olõtọ ododo ni: iwọ, olõtọ-julọ, ti wọ̀n ipa-ọ̀na awọn olõtọ. Nitõtọ, Oluwa, li ọ̀na idajọ rẹ, li awa duro de ọ: ifẹ́ ọkàn wa ni si orukọ rẹ, ati si iranti rẹ. Ọkàn mi li emi fi ṣe afẹ̃ri rẹ li oru; nitõtọ, pẹlu ẹmi mi ninu mi li emi o wá ọ ni kutùkutù; nitori nigbati idajọ rẹ mbẹ ni ilẹ, awọn ti mbẹ li aiye yio kọ́ ododo. Bi a ba fi ojurere hàn enia buburu, kì yio kọ́ ododo: ni ilẹ iduroṣinṣin li on o hùwa aiṣõtọ, kì yio si ri ọlanla Oluwa. Oluwa, ọwọ́ rẹ gbe soke, nwọn kì yio ri, ṣugbọn nwọn o ri, oju o si tì wọn nitori ilara wọn si awọn enia; nitõtọ, iná awọn ọta rẹ yio jẹ wọn run.
Kà Isa 26
Feti si Isa 26
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 26:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò