Isa 26:1-11

Isa 26:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò náà, orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé: “A ní ìlú tí ó lágbára, ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò. Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè, kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé. O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae, nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀, ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀, ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata, ó fà á sọ sinu eruku. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.” Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodo ó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán. Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA, orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́. Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́, mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọ nítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyé ni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo. Bí a bá ṣàánú ẹni ibi, kò ní kọ́ láti ṣe rere. Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo, kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA. OLUWA o ti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti jẹ àwọn ọ̀tá níyà, ṣugbọn wọn kò rí i. Jẹ́ kí wọn rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn eniyan rẹ jẹ ọ́ lógún, kí ojú sì tì wọ́n. Jẹ́ kí iná tí o dá fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.

Isa 26:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda: Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀. Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́. Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA títí láé, nítorí OLúWA, OLúWA ni àpáta ayérayé náà. Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀. Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹsẹ̀ aninilára n nì, ipasẹ̀ àwọn òtòṣì. Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú Ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere. Bẹ́ẹ̀ ni, OLúWA, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti sọ òdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọláńlá OLúWA sí. OLúWA, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.