AISAYA 21:1-10

AISAYA 21:1-10 YCE

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa aṣálẹ̀ etí òkun nìyí: àjálù kan ń já bọ̀ láti inú aṣálẹ̀, láti ilẹ̀ tí ó bani lẹ́rù, ó ń bọ̀ bí ìjì líle tí ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá aṣálẹ̀. Ìran tí a fi hàn mí yìí le: Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun, abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́. Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ! Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun! Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí, gbogbo ara ní ń ro mí bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́. A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan, wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran. Ọkàn mi dààmú, jìnnìjìnnì dà bò mí; wọ́n ti sọ àfẹ̀mọ́júmọ́ tí mò ń retí di ìbẹ̀rù mọ́ mi lọ́wọ́. Wọ́n tẹ́ tabili, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sílẹ̀ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu. Ariwo bá ta pé “Ẹ gbéra nílẹ̀, ẹ̀yin ológun! Ẹ fepo pa asà yín.” Nítorí OLUWA wí fún mi pé: “Lọ fi aṣọ́nà ṣọ́ ojú ọ̀nà, kí ó máa kéde ohun tí ó bá rí. Nígbà tí ó bá rí àwọn ẹlẹ́ṣin tí wọn ń bọ̀ ní meji-meji, bí ó bá rí i tí àwọn kan gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí àwọn kan gun ràkúnmí, kí ó fara balẹ̀ dáradára, kí ó dẹtísílẹ̀ dáradára.” Ẹni tí ń ṣọ́nà kígbe pé: “OLUWA mi, lórí ilé-ìṣọ́ ni èmi í dúró sí lojoojumọ, níbi tí a fi mí ṣọ́, ni èmi í sì í wà ní òròòru. Ẹ wò ó! Àwọn ẹlẹ́ṣin kan ń bọ̀, wọ́n fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ní meji-meji!” “Ẹ gbọ́! Ìlú Babiloni ti wó! Ó ti wó! Pẹlu gbogbo àwọn oriṣa rẹ̀, ó ti wó lulẹ̀ patapata.” Ẹ̀yin eniyan mi tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, bí ẹni tẹ ọkà ní ibi ìpakà, ohun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ní mò ń kéde fun yín yìí.