AISAYA 11

11
Ìjọba Tí Ó Tòrò
1Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese,
ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.#Ifi 5:5; 22:16
2Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e,
ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye,
ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára,
ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA.
3Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀
kì í ṣe ohun tí ó fojú rí,
tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́.
4Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka,#2 Tẹs 2:8
yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀,
yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán,
yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.
5Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀,#Efe 6:14
yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀.
6Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé,
àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́,
ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀,
ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ.
7Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀,
àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀,
kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù.
8Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀,
ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú
yóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò.
9Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́,
tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi.#Ais 65:25 Heb 2:14
Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé
bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.
Àwọn Ìgbèkùn Yóo Pada
10Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.#Rom 5:12 11Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.
12Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ.
Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ,
láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé.
13Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò,
a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run.
Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ.
14Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn,
wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn.
Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu.
Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.
15OLUWA yóo pa Ijipti run patapata.#Ifi 16:12
Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati,
yóo sì pín in sí ọ̀nà meje,
kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá.
16Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀;
bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli,
nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀