1
AISAYA 11:2-3
Yoruba Bible
Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA. Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀ kì í ṣe ohun tí ó fojú rí, tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 11:2-3
2
AISAYA 11:1
Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese, ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 11:1
3
AISAYA 11:4
Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀, yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán, yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.
Ṣàwárí AISAYA 11:4
4
AISAYA 11:5
Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀, yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀.
Ṣàwárí AISAYA 11:5
5
AISAYA 11:9
Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́, tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi. Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.
Ṣàwárí AISAYA 11:9
6
AISAYA 11:6
Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́, ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀, ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ.
Ṣàwárí AISAYA 11:6
7
AISAYA 11:10
Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.
Ṣàwárí AISAYA 11:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò