AISAYA 10

10
1Àwọn tí ń ṣe òfin tí kò tọ́ gbé!
Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn akọ̀wé, tí ń kọ̀wé láti ni eniyan lára;
2wọ́n ń dínà ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní,
wọn kò sì jẹ́ kí àwọn talaka ààrin àwọn eniyan mi rí ẹ̀tọ́ wọn gbà,
kí wọ́n lè sọ àwọn opó di ìkógun.
3Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yín
tí ìparun bá dé láti òkèèrè?
Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́?
Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí?
4Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun,
tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú.
Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.
Asiria ṣe Àṣejù
5Háà! Asiria!
Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pá
nígbà tí inú bá bí mi.
6Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun,
ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú.
Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù.
Kí wọ́n kó wọn lẹ́rú
kí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀
tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba.
7Ṣugbọn ọba Asiria kò pa irú ète yìí,
kò sì ní irú èrò yìí lọ́kàn;
gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè run
8nítorí ó wí pé:
“Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn olórí ogun mi!
9Ṣebí bíi Kakemiṣi ni Kalino rí,
tí Hamati rí bíi Aripadi,
tí Samaria kò sì yàtọ̀ sí Damasku?
10Bí ọwọ́ mi ṣe tẹ àwọn ìlú àwọn abọ̀rìṣà,
tí oriṣa wọn lágbára ju ti Jerusalẹmu ati Samaria lọ,
11ṣé n kò ní lè ṣe sí Jerusalẹmu ati àwọn oriṣa rẹ̀
bí mo ti ṣe Samaria ati àwọn oriṣa rẹ̀?”
12Nígbà tí OLUWA bá parí bírà tí ó ń dá ní òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu,
yóo fìyà jẹ ọba Asiria fún ìwà ìgbéraga ati àṣejù rẹ̀.
13Nítorí ó ní,
“Agbára mi ni mo fi ṣe èyí,
ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe é
nítorí pé mo jẹ́ amòye.
Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada,
mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn.
Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin.
14Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,
bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ.
Mo kó gbogbo ayé,
bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ,
kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan,
kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.”
15Ǹjẹ́ fáàrí àáké lè pọ̀ ju ti ẹni tí ó ń fi gégi lọ?
Tabi ayùn lè fọ́nnu sí ẹni tí ó ń fi rẹ́ igi?
Ǹjẹ́ kùmọ̀ lè mú ẹni tí ó ń lò ó lọ́wọ́,
tabi kí ọ̀pá mú ẹni tí ó ni í lọ́wọ́?
16Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirun
sí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀.
Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo,
ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni.
17Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóo di iná,
Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóo di ahọ́n iná;
yóo sì jó àwọn ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan.
18OLUWA yóo pa àwọn igi ńlá inú igbó rẹ̀ run,
yóo pa àwọn igi eléso ilẹ̀ rẹ́ tèsotèso,
bí ìgbà tí àrùn bá gbẹ eniyan.
19Ohun tí yóo kù ninu àwọn igi igbó rẹ̀
kò ní ju ohun tí ọmọde lè kà, kí ó sì kọ sílẹ̀ lọ.
Àwọn Díẹ̀ Yóo Pada Wá
20Ní ọjọ́ náà, ìyókù Israẹli ati àwọn tí yóo yè ní agbo ilé Jakọbu, kò ní gbé ara lé ẹni tí ó ṣá wọn lọ́gbẹ́ mọ́, ṣugbọn OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni wọn óo fẹ̀yìn tì ní òtítọ́. 21Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára. 22Israẹli, bí àwọn eniyan rẹ tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, díẹ̀ ninu wọn ni yóo pada, nítorí ìparun ti di òfin ó sì kún fún òdodo 23Nítorí OLUWA, OLUWA, àwọn ọmọ ogun yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeparí láàrin gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é lófin.#Rom 9:27
OLUWA Yóo Jẹ Asiria Níyà
24Nítorí náà OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi tí ń gbé Sioni, Ẹ má bẹ̀rù àwọn ará Asiria bí wọn bá fi ọ̀gọ lù yín, tabi tí wọn gbé ọ̀pá sókè si yín bí àwọn ará Ijipti ti ṣe si yín. 25Nítorí pé láìpẹ́, ibinu mi si yín yóo kásẹ̀ nílẹ̀, n óo sì dojú ibinu mi kọ wọ́n láti pa wọ́n run. 26Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, n óo fi ọ̀pá mi nà wọ́n, bí ìgbà tí mo na àwọn ará Midiani ní ibi àpáta Orebu. Ọ̀pá rẹ̀ yóo wà lórí òkun. Yóo tún gbé e sókè bí ó ti ṣe ní Ijipti. 27Ní ọjọ́ náà, a óo gbé ẹrù tí ó dì lé ọ lórí kúrò, a óo sì fa àjàgà rẹ̀ dá kúrò lọ́rùn rẹ.”
Ọ̀tá Kọlu Jerusalẹmu
28Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni,
ó ti dé sí Aiati;
ó kọjá ní Migironi,
ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi.
29Wọ́n sọdá sí òdìkejì odò
wọ́n sùn ní Geba di ọjọ́ keji.
Àwọn ará Rama ń wárìrì,
àwọn ará Gibea, ìlú Saulu sá lọ.
30Kígbe! Ìwọ ọmọbinrin Galimu.
Fetí sílẹ̀ ìwọ Laiṣa,
kí Anatoti sì dá a lóhùn.
31Madimena ń sá lọ,
àwọn ará Gebimu ń sá àsálà.
32Ní òní olónìí, yóo dúró ní Nobu,
yóo di ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn òkè Sioni,
àní òkè Jerusalẹmu.
33Ẹ wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun,
yóo gé àwọn ẹ̀ka igi náà pẹlu agbára tí ó bani lẹ́rù.
Yóo gé àwọn tí ó ga fíofío lulẹ̀,
yóo sì rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.
34Yóo fi àáké gé àwọn igi igbó tí ó dí,#Ais 14:24-27; Neh 1:1-3, 19; Sef 2:13-15
Lẹbanoni pẹlu gbogbo igi ńláńlá rẹ̀ yóo sì wó.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀