ISIKIẸLI 18

18
Iṣẹ́ Ẹnìkọ̀ọ̀kan
1OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó bi mí pé: 2“Kí ni ẹ rí tí ẹ fi ń pa irú òwe yìí nípa ilẹ̀ Israẹli, tí ẹ̀ ń sọ pé,
‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà tí ó kan,
ni eyín fi kan àwọn ọmọ?’ #Jer 31:29
3“Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní pa òwe yìí mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. 4Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.
5“Bí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olódodo, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu; 6bí kò bá bá wọn jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tabi kí ó bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli; tí kò bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, tabi kí ó bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́; 7tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, ṣugbọn tí ó dá ohun tí onígbèsè fi ṣe ìdúró pada fún un; tí kò fi ipá jalè, tí ó ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò, 8tí kò gba owó èlé lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ láàrin ẹni meji, 9tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. #Lef 18:5
10“Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí ń fi ipá jalè, tí ń pa eniyan, tí kò ṣe ọ̀kankan ninu gbogbo ohun tí a kà sílẹ̀ pé baba ń ṣe, 11ṣugbọn tí ó ń jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí ó ń bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀; 12tí ń ni talaka ati aláìní lára, tí ń fi ipá jalè, tí kì í dá ohun tí onígbèsè rẹ̀ bá fi ṣe ìdúró pada fún un, tí ń bọ oriṣa, tí ń ṣe ohun ìríra, 13tí ń gba owó èlé; ǹjẹ́ irú eniyan bẹ́ẹ̀ lè yè? Kò lè yè rárá. Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra wọnyi, yóo kú ni dájúdájú; lórí ara rẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.
14“Ṣugbọn bí eniyan burúkú yìí bá bí ọmọ, tí ọmọ yìí rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ń dá, tí ẹ̀rù bà á, tí kò sì ṣe bíi baba rẹ̀, 15tí kì í jẹ ẹbọ lórí àwọn òkè, tí kò bọ àwọn oriṣa ilé Israẹli, tí kò bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀, 16tí kò ṣẹ ẹnikẹ́ni; tí Kì í gba ohun ìdúró lọ́wọ́ onígbèsè, tí kì í fi ipá jalè, ṣugbọn tí ń fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí sì ń da aṣọ bo ẹni tí ó wà ní ìhòòhò, 17tí ó yàgò fún ẹ̀ṣẹ̀, tí kì í gba owó èlé, tí ń pa òfin mi mọ́, tí sì ń rìn ninu ìlànà mi, kò ní kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, dájúdájú yóo yè. 18Baba rẹ̀ yóo kú ní tirẹ̀, nítorí pé ó ń fi ipá gbowó, ó ń ja arakunrin rẹ̀ lólè, ó sì ń ṣe ohun tí kò dára sí àwọn eniyan rẹ̀; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni yóo ṣe kú.
19“Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí ló dé tí ọmọ kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ bá ti ṣe ohun tí ó bá òfin mu, tí ó sì ti mú gbogbo ìlànà mi ṣẹ; dájúdájú yóo yè ni. 20Ẹni tí ó bá ṣẹ̀ ni yóo kú: ọmọ kò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀; baba kò sì ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo yóo jèrè òdodo rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan burúkú yóo jèrè ìwà burúkú rẹ̀. #Diut 24:16
21“Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú. 22A kò ní ranti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóo yè nítorí òdodo rẹ̀.” 23OLUWA ní: “A máa ṣe pé mo ní inú dídùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni? Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò lọ́nà burúkú rẹ̀, kí ó sì yè.
24“Ṣugbọn bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, tí ó ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn eniyan burúkú ń ṣe; ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ leè yè? Rárá! A kò ní ranti gbogbo òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe mọ́, yóo kú nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ ati ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
25“Sibẹsibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli: ọ̀nà tèmi ni kò tọ́ ni, àbí ọ̀nà tiyín? 26Bí olódodo bá yipada kúrò ninu ìwà òdodo rẹ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. 27Bí eniyan burúkú bá sì yipada kúrò ninu ìwà ibi rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là. 28Nítorí pé ó ronú, ó sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ń dá, dájúdájú yóo yè, kò ní kú. 29Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, ‘Ọ̀nà OLUWA kò tọ́.’ Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ọ̀nà mi ni kò tọ́, àbí tiyín?
30“Nítorí náà, n óo da yín lẹ́jọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Ìwà olukuluku ni n óo fi dá a lẹ́jọ́. Ẹ ronupiwada, kí ẹ sì yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà pa yín run. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 31Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli? 32N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” #Ọgb 1:13

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 18: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀