1
ISIKIẸLI 18:32
Yoruba Bible
N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ISIKIẸLI 18:32
2
ISIKIẸLI 18:20
Ẹni tí ó bá ṣẹ̀ ni yóo kú: ọmọ kò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀; baba kò sì ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ rẹ̀. Olódodo yóo jèrè òdodo rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan burúkú yóo jèrè ìwà burúkú rẹ̀.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 18:20
3
ISIKIẸLI 18:31
Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli?
Ṣàwárí ISIKIẸLI 18:31
4
ISIKIẸLI 18:23
OLUWA ní: “A máa ṣe pé mo ní inú dídùn sí ikú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni? Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò lọ́nà burúkú rẹ̀, kí ó sì yè.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 18:23
5
ISIKIẸLI 18:21
“Ṣugbọn bí eniyan burúkú bá yipada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń dá, tí ó ń pa òfin mi mọ́, tí ó ń ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì bá òfin mu, dájúdájú yóo yè ni, kò ní kú.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 18:21
6
ISIKIẸLI 18:9
tí ó ń rìn ninu ìlànà mi, tí ó sì ń fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, olódodo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo sì yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 18:9
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò