ISIKIẸLI 19

19
Orin Arò
1OLUWA ní kí n sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn nítorí àwọn olórí Israẹli, 2kí n sọ pé:
Abo kinniun pataki ni ìyá rẹ láàrin àwọn kinniun!
Ó dùbúlẹ̀ láàrin àwọn ọ̀dọ́ kinniun,
ó ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3Ó tọ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà;
ó di ọ̀dọ́ kinniun.
Ó kọ́ ọ bí wọ́n tí ń ṣe ọdẹ,
ó sì ń pa eniyan jẹ.
4Àwọn eniyan ayé gbọ́ nípa rẹ̀,
wọ́n tàn án sinu kòtò wọn.
Wọ́n fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú,
wọ́n sì fà á lọ sí ilẹ̀ Ijipti.
5Nígbà tí abo kinniun náà rí i pé ọwọ́ tẹ ọmọ òun,
ati pé igbẹkẹle òun ti dòfo,
ó mú òmíràn ninu àwọn ọmọ rẹ̀,
ó tọ́ ọ di ọ̀dọ́ kinniun.
6Ó ń yan kiri láàrin àwọn kinniun;
nítorí ó ti di ọ̀dọ́ kinniun tí ó lágbára,
ó kọ́ bí wọn tí ń ṣe ọdẹ,
ó sì ń pa eniyan jẹ.
7Ó wó ilé ìṣọ́ wọn lulẹ̀;
ó sọ ìlú wọn di ahoro.
Ẹ̀rù ba gbogbo Ilẹ̀ náà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀,
nígbà tí wọ́n gbọ́ bíbú rẹ̀.
8Àwọn orílẹ̀-èdè bá dójú lé e,
wọ́n dẹ tàkúté fún un ní gbogbo ọ̀nà,
wọ́n da àwọ̀n wọn bò ó,
wọ́n sì mú un ninu kòtò tí wọn gbẹ́ fún un.
9Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,
wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,
wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.
Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,
kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.
10Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbà
tí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;
ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,
nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.
11Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbára
ni a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.
Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.
Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.
12Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,
a sì jù ú sílẹ̀.
Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,
gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.
Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.
13Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀,
ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi.
14Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀,
ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀.
Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́,
tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba.
Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀