ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:18-20

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3:18-20 YCE

Mo wí ní ọkàn ara mi pé Ọlọrun ń dán àwọn ọmọ eniyan wò, láti fihàn wọ́n pé wọn kò yàtọ̀ sí ẹranko; nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí.