ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3

3
Ohun Gbogbo ni Ó ní Àkókò Tirẹ̀
1Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀:
2àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà;
àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà.
3Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà,
àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà.
4Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà;
àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà.
5Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà;
àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà.
6Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà;
àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà.
7Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà;
àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà.
8Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà;
àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà.
9Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́?
10Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan. 11Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 12Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; 13ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀.
14Mo mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe, yóo wà títí lae. Kò sí ohun tí ẹ̀dá lè fi kún un, tabi tí ẹ̀dá lè yọ kúrò níbẹ̀, Ọlọrun ni ó dá a bẹ́ẹ̀ kí eniyan lè máa bẹ̀rù rẹ̀. 15Ohunkohun tí ó wà, ó ti wà tẹ́lẹ̀, èyí tí yóo sì tún wà, òun pàápàá ti wà rí; Ọlọrun yóo ṣe ìwádìí gbogbo ohun tí ó ti kọjá.
Ìwà Àìtọ́ Tí Eniyan Ń Hù.
16Mo rí i pé ninu ayé yìí ibi tí ó yẹ kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo wà ibẹ̀ gan-an ni ìwà ìkà wà. 17Mo wí ní ọkàn ara mi pé, Ọlọrun yóo dájọ́ fún olódodo ati fún eniyan burúkú; nítorí ó ti yan àkókò fún ohun gbogbo ati fún iṣẹ́ gbogbo. 18Mo wí ní ọkàn ara mi pé Ọlọrun ń dán àwọn ọmọ eniyan wò, láti fihàn wọ́n pé wọn kò yàtọ̀ sí ẹranko; 19nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin òpin eniyan ati ti ẹranko. Bí eniyan ṣe ń kú, ni ẹranko ṣe ń kú. Èémí kan náà ni wọ́n ń mí; eniyan kò ní anfaani kankan ju ẹranko lọ; nítorí pé asán ni ohun gbogbo. 20Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ; inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá, inú erùpẹ̀ ni wọn yóo sì pada sí. 21Ta ló mọ̀ dájúdájú, pé ẹ̀mí eniyan a máa gòkè lọ sọ́run; tí ti ẹranko sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sinu ilẹ̀? 22Nítorí náà, mo rí i pé kò sí ohun tí ó dára, ju pé kí eniyan jẹ ìgbádùn iṣẹ́ rẹ̀ lọ, nítorí ìpín tirẹ̀ ni. Ta ló lè dá eniyan pada sáyé, kí ó wá rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá ti kú?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa