ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4

4
1Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé.
Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára,
Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu.
Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí,
kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu.
2Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú,
ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ.
3Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá,
sàn ju ti àwọn mejeeji lọ,
nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibi
tí àwọn ọmọ aráyé ń ṣe.
4Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.
5Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera,
tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú.
6Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyà
ju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ.
7Mo tún rí ohun asán kan láyé:
8Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan,
kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan,
sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin,
bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀.
Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fún
tí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?”
Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo.
9Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ,
nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́,
èrè wọn yóo sì pọ̀.
10Bí ọ̀kan bá ṣubú,
ekeji yóo gbé e dìde.
Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé!
Nítorí nígbà tí ó bá ṣubú
kò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde.
11Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀,
wọn yóo fi ooru mú ara wọn
ṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀?
12Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ,
nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀.
Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.
13Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ, 14kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i. 15Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba. 16Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ONÍWÀÁSÙ 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa