Mo wi li aiya mi niti ìwa awọn ọmọ enia; ki Ọlọrun ki o le fi wọn hàn, ati ki nwọn ki o le ri pe ẹran ni awọn tikalawọn fun ara wọn. Nitoripe ohun ti nṣe ọmọ enia nṣe ẹran; ani ohun kanna li o nṣe wọn: bi ekini ti nkú bẹ̃li ekeji nkú; nitõtọ ẹmi kanna ni gbogbo wọn ní, bẹ̃li enia kò li ọlá jù ẹran lọ: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀. Nibikanna ni gbogbo wọn nlọ; lati inu erupẹ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn si tun pada di erupẹ.
Kà Oni 3
Feti si Oni 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Oni 3:18-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò