ÀWỌN ỌBA KEJI 16
16
Ahasi, Ọba Juda
(2Kron 28:1-27)
1Ní ọdún kẹtadinlogun tí Peka, ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Ahasi, ọmọ Jotamu, jọba ní Juda. 2Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere Dafidi baba ńlá rẹ̀, ṣugbọn ó ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, 3nípa títẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọba Israẹli. Òun náà tilẹ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè oníwà burúkú tí OLUWA lé kúrò lórí ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Israẹli. 4Ní gbogbo ibi gíga, ati àwọn orí òkè ati abẹ́ gbogbo igi ni Ahasi tií máa rúbọ, tíí sìí sun turari.#Diut 12:31
5Resini, ọba Siria, ati Peka, ọba Israẹli, gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó ti Ahasi, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.#Ais 7:1 6Ní àkókò kan náà ni ọba Edomu gba Elati pada, ó sì lé àwọn ará Juda tí wọn ń gbé ibẹ̀, àwọn ará Edomu sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní olónìí. 7Ahasi ranṣẹ lọ bá Tigilati Pileseri, ọba Asiria, ó ní, “Iranṣẹ ati ọmọ rẹ ni mo jẹ́, nítorí náà, jọ̀wọ́ wá gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọba Siria ati ti Israẹli tí wọ́n gbógun tì mí.” 8Ahasi kó fadaka ati wúrà tí ó wà ninu ilé OLUWA, ati tinú àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin jọ, ó kó o ranṣẹ sí ọba Asiria. 9Ọba Asiria gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì gbógun ti Damasku, ó ṣẹgun rẹ̀, ó pa Resini ọba, ó sì kó gbogbo àwọn eniyan ìlú náà lẹ́rú lọ sí Kiri.
10Nígbà tí Ahasi lọ pàdé Tigilati Pileseri ọba, ní Damasku, ó rí pẹpẹ ìrúbọ kan níbẹ̀, ó sì ranṣẹ sí Uraya alufaa pé kí ó mọ irú rẹ̀ gan-an láìsí ìyàtọ̀ kankan. 11Ki Ahasi tó dé, Uraya bá mọ irú pẹpẹ ìrúbọ náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ahasi rán sí i láti Damasku. 12Nígbà tí Ahasi pada dé, o rí i pé Uraya ti mọ pẹpẹ ìrúbọ náà; ó lọ sí ìdí rẹ̀, 13ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí rẹ̀. Ó rú ẹbọ ohun mímu, ó sì da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ alaafia rẹ̀ sí ara rẹ̀. 14Pẹpẹ idẹ tí a ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA wà ní ààrin pẹpẹ tirẹ̀ ati ilé OLUWA. Nítorí náà, Ahasi gbé pẹpẹ idẹ náà sí apá òkè pẹpẹ tirẹ̀.#Eks 27:1-2; 2Kron 4:1 15Lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún Uraya alufaa, ó ní, “Máa lo pẹpẹ ìrúbọ tí ó tóbi yìí fún ẹbọ sísun àárọ̀ ati ẹbọ ohun jíjẹ ìrọ̀lẹ́, ati fún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọba, ati fún ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu ti àwọn eniyan. Kí o sì máa da ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá pa fún ìrúbọ sí orí rẹ̀. Ṣugbọn gbé pẹpẹ ìrúbọ idẹ tọ̀hún sọ́tọ̀ fún mi kí n lè máa lò ó láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ OLUWA.” 16Uraya sì ṣe bí Ahasi ọba ti pa á láṣẹ fún un.
17Ahasi gé àwọn ẹsẹ̀ idẹ ti agbada ńlá, ó gbé agbada náà kúrò. Ó tún gbé agbada omi ńlá tí a fi idẹ ṣe, tí wọ́n gbé ka ẹ̀yìn àwọn akọ mààlúù idẹ mejila, ó sì gbé e lé orí ìpìlẹ̀ tí a fi òkúta ṣe. 18Nítorí pé Ahasi fẹ́ tẹ́ ọba Asiria lọ́rùn, ó gbé pátákó tí wọ́n tẹ́ fún ìtẹ́ ọba kúrò, ó sì sọ ibẹ̀ dí ẹnu ọ̀nà tí ọba ń gbà wọ ilé OLUWA.#1A. Ọba 7:23-39; 2Kron 4:2-6
19Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 20Ahasi kú, wọn sì sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Hesekaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.#Ais 14:28
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ỌBA KEJI 16: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010