ÀWỌN ỌBA KEJI 15

15
Asaraya Ọba Juda
(2Kron 26:1-23)
1Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Jeroboamu jọba ní Israẹli ni Asaraya ọmọ Amasaya, jọba ní Juda. 2Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀. 3Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Amasaya, baba rẹ̀. 4Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run, àwọn eniyan ṣì ń rúbọ; wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. 5OLUWA sọ Asaraya ọba di adẹ́tẹ̀, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó ń dá gbé. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì ń ṣàkóso ìjọba nípò rẹ̀.
6Gbogbo nǹkan yòókù tí Asaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 7Ó kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Jotamu, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.#Ais 6:1
Sakaraya Ọba Israẹli
8Ní ọdún kejidinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda ni Sakaraya ọmọ Jeroboamu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún oṣù mẹfa. 9Ó ṣe ohun burúkú níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe. Ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu; ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. 10Ṣalumu ọmọ Jabeṣi dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó pa á ní Ibileamu, ó sì jọba dípò rẹ̀.
11Gbogbo nǹkan yòókù tí Sakaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
12OLUWA ṣèlérí fún Jehu pé, “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóo jọba ní Israẹli.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.#2A. Ọba 10:30
Ṣalumu Ọba Israẹli
13Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya ti jọba ní Juda ni Ṣalumu, ọmọ Jabeṣi, jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó wà lórí oyè fún oṣù kan.
14Menahemu ọmọ Gadi lọ sí Samaria láti Tirisa, ó pa Ṣalumu ọba, ó sì jọba dípò rẹ̀. 15Gbogbo nǹkan yòókù tí Ṣalumu ṣe, ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. 16Ní àkókò náà Menahemu pa ìlú Tapua run, ati àwọn ìlú tí wọ́n yí i ká láti Tirisa, nítorí pé wọn kò ṣí ìlẹ̀kùn ìlú náà fún un, ó sì la inú gbogbo àwọn aboyún tí wọ́n wà níbẹ̀.
Menahemu Ọba Israẹli
17Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda, ni Menahemu, ọmọ Gadi, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹ́wàá. 18Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. 19Pulu, tí à ń pè ní Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli; kí ó baà lè ran Menahemu lọ́wọ́ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, Menahemu fún un ní ẹgbẹrun (1,000) talẹnti owó fadaka. 20Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.
21Gbogbo nǹkan yòókù tí Menahemu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. 22Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀, Pekahaya, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Pekahaya, Ọba Israẹli
23Nígbà tí ó di aadọta ọdún tí Asaraya jọba ní Juda, ni Pekahaya, ọmọ Menahemu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji. 24Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA; ó sì tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. 25Peka, ọmọ Remalaya, olórí ogun rẹ̀, pẹlu aadọta ọmọ ogun Gileadi dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní Samaria, ninu ilé tí a mọ odi tí ó lágbára yíká, tí ó wà ninu ààfin rẹ̀, Peka sì jọba dípò rẹ̀.
26Gbogbo nǹkan yòókù tí Pekahaya ṣe, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
Peka Ọba Israẹli
27Ní ọdún kejilelaadọta tí Asaraya jọba ní Juda, ni Peka, ọmọ Remalaya, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ogún ọdún. 28Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.
29Ní àkókò tí Peka jọba Israẹli ni Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gba ìlú Ijoni, Abeli Beti Maaka, Janoa, Kedeṣi, Hasori, ati ilẹ̀ Gileadi, Galili ati gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rú lọ sí Asiria.
30Ní ogún ọdún tí Jotamu, ọmọ Usaya jọba Juda, ni Hoṣea, ọmọ Ela, dìtẹ̀ mọ́ Peka ọba, ó pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀. 31Gbogbo nǹkan yòókù tí Peka ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
Jotamu, Ọba Juda
(2Kron 27:1-9)
32Ní ọdún keji tí Peka ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Jotamu, ọmọ Usaya, jọba ní Juda. 33Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọ Sadoku. 34Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀ sí ọ̀nà Usaya, baba rẹ̀. 35Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA.
36Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 37Ní àkókò tí ó jọba ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí rán Resini, ọba Siria, ati Peka, ọmọ Remalaya, tí í ṣe ọba Israẹli, láti gbógun ti Juda. 38Jotamu kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi; Ahasi ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 15: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀