ÀWỌN ỌBA KEJI 14

14
Amasaya Ọba Juda
(2Kron 25:1-24)
1Ní ọdún keji tí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi jọba ní Israẹli ni Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda. 2Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Jehoadini, ará Jerusalẹmu, ni ìyá rẹ̀. 3Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò dàbí ti Dafidi baba ńlá rẹ̀; ohun gbogbo tí Joaṣi baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe. 4Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run; àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń sun turari.
5Nígbà tí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ tán, ó pa àwọn olórí ogun tí wọ́n pa baba rẹ̀. 6Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn nítorí pé òfin Mose pa á láṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba. Olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”#Diut 24:16
7Amasaya pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó ṣẹgun Sela, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jokiteeli, orúkọ yìí ni ìlú náà ń jẹ́ títí di òní yìí.
8Lẹ́yìn náà, Amasaya ranṣẹ sí Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli, láti pè é níjà sí ogun. 9Ṣugbọn Jehoaṣi ọba ranṣẹ pada pẹlu òwe yìí: Ó ní, “Ní ìgbà kan ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún kan tí ó wà ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Fi ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi ní aya.’ Ṣugbọn ẹranko burúkú kan tí ó wà ní Lẹbanoni ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀. 10Nisinsinyii, ìwọ Amasaya, nítorí pé o ti ṣẹgun Edomu, ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ògo rẹ yìí tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ló dé tí o fi fẹ́ dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ sí ìparun ara rẹ ati ti Juda?”
11Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda. 12Israẹli ṣẹgun Juda, gbogbo àwọn ọmọ ogun Juda sì pada sí ilé wọn. 13Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita). 14Ó kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí ati gbogbo àwọn ohun èlò ilé OLUWA ati gbogbo ohun tí ó níye lórí ní ààfin, ó sì pada sí Samaria.
15Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe, ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya jà, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. 16Jehoaṣi kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Ikú Amasaya Ọba Juda
(2Kron 25:25-28)
17Amasaya ọba, ọmọ Joaṣi gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọba Israẹli. 18Gbogbo nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.
19Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á. 20Wọ́n gbé òkú rẹ̀ sórí ẹṣin wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi. 21Àwọn eniyan Juda sì fi Asaraya, ọmọ rẹ̀, jọba. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni, nígbà tí ó jọba. 22Asaraya tún ìlú Elati kọ́, ó sì dá a pada fún Juda lẹ́yìn ikú baba rẹ̀.
Jeroboamu Keji, Ọba Israẹli
23Ní ọdún kẹẹdogun tí Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda ni Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli jọba ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkanlelogoji. 24Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA; ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀. 25Ó gba gbogbo ilẹ̀ Israẹli pada láti ẹnubodè Hamati títí dé Òkun Araba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ láti ẹnu wolii rẹ̀, Jona, ọmọ Amitai, ará Gati Heferi.#Jona 1:1
26OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. 27Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò tíì sọ pé òun óo pa gbogbo Israẹli run, nítorí náà, ó ṣẹgun fún wọn láti ọwọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi.
28Gbogbo nǹkan yòókù tí Jeroboamu ṣe, ìwà akọni rẹ̀ lójú ogun ati bí ó ti gba Damasku ati Hamati, tí wọ́n jẹ́ ti Juda tẹ́lẹ̀ rí, fún Israẹli, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. 29Jeroboamu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba, Sakaraya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 14: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀