ÀWỌN ỌBA KEJI 17

17
Hoṣea Ọba Israẹli
1Ní ọdún kejila tí Ahasi jọba ní Juda, ni Hoṣea ọmọ Ela jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì jọba fún ọdún mẹsan-an. 2Ó ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò tó ti àwọn ọba tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀. 3Ṣalimaneseri Ọba Asiria gbógun tì í; Hoṣea bá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún un, ó sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un ní ọdọọdún. 4Ṣugbọn ní ọdún kan, Hoṣea ranṣẹ sí So, ọba Ijipti pé, kí ó ran òun lọ́wọ́, kò sì san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria mọ́. Nígbà tí Ṣalimaneseri gbọ́, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ju Hoṣea sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ìṣubú Samaria
5Lẹ́yìn náà, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli, ó dó ti Samaria fún ọdún mẹta. 6Ní ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba, ọba Asiria ṣẹgun Samaria, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. Ó kó wọn sí ìlú Hala ati sí etí odò Habori tí ó wà ní agbègbè Gosani, ati sí àwọn ìlú Media.
7Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wọn ó gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Farao, tí ó sì kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Wọ́n ti bọ oriṣa, 8wọ́n sì tẹ̀lé ìwà àwọn eniyan tí OLUWA lé jáde kúrò fún wọn, ati àwọn àṣàkaṣà tí àwọn ọba Israẹli kó wá. 9Àwọn ọmọ Israẹli ṣe oríṣìíríṣìí nǹkan níkọ̀kọ̀, tí OLUWA Ọlọrun wọn kò fẹ́. Wọ́n kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sinu àwọn ìlú wọn: wọ́n kọ́ sinu ilé ìṣọ́, títí kan àwọn ìlú olódi. 10Wọ́n gbé àwọn òpó tí a fi òkúta ṣe ati àwọn ère Aṣerimu sí orí àwọn òkè ati sí abẹ́ àwọn igi tí wọ́n ní ìbòòji. 11Wọ́n ń sun turari ní gbogbo orí òkè, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Wọ́n mú kí ibinu OLUWA ru pẹlu ìwà burúkú wọn, 12wọ́n sì lòdì sí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn pé wọn kó gbọdọ̀ bọ oriṣa.#1A. Ọba 14:23
13Sibẹ, OLUWA ń rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn wolii rẹ̀ kí wọ́n máa kìlọ̀ fún Israẹli ati Juda pé, “Ẹ kọ ọ̀nà burúkú yín sílẹ̀ kí ẹ sì pa òfin ati ìlànà mi, tí mo fún àwọn baba ńlá yín mọ́; àní àwọn tí mo fun yín nípasẹ̀ àwọn wolii, iranṣẹ mi.” 14Ṣugbọn wọn kò gbọ́, wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn líle bí àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò gba OLUWA Ọlọrun wọn gbọ́. 15Wọ́n kọ ìlànà rẹ̀, wọn kò pa majẹmu tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá mọ́, wọn kò sì fetí sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń sin oriṣa lásánlàsàn, àwọn pàápàá sì di eniyan lásán. Wọ́n tẹ̀ sí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká; wọ́n kọ òfin tí OLUWA ṣe fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà wọn. 16Wọ́n rú gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun wọn; wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meji, wọ́n ń sìn wọ́n. Wọ́n gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, wọ́n sì ń bọ àwọn ohun tí ó wà lójú ọ̀run ati oriṣa Baali. 17Wọ́n fi àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn rú ẹbọ sísun sí oriṣa, wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì fi ara wọn jì láti ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n sì fi bẹ́ẹ̀ rú ibinu rẹ̀ sókè. 18Nítorí náà, OLUWA bínú sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, ṣugbọn ó fi Juda nìkan sílẹ̀.#1A. Ọba 12:28 #Diut 18:10
19Sibẹ, àwọn ará Juda kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n tẹ̀lé ìwà tí àwọn ọmọ Israẹli ń hù. 20OLUWA bá kọ gbogbo àwọn ìran Israẹli sílẹ̀, ó jẹ wọ́n níyà, ó sì fi wọ́n lé àwọn apanirun lọ́wọ́ títí wọ́n fi pa wọn run níwájú rẹ̀.
21Lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ìyapa sí ààrin Israẹli ati ìdílé Dafidi, Israẹli fi Jeroboamu ọmọ Nebati jọba. Jeroboamu mú kí wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, ó sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá. 22Àwọn ọmọ Israẹli ń tẹ̀lé gbogbo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, wọn kò sì yipada kúrò ninu wọn, 23títí tí OLUWA fi run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, bí ó ti kìlọ̀ fún wọn láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Asiria ṣe kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Asiria, níbi tí wọ́n wà títí di òní olónìí.
Àwọn Ará Asiria Bẹ̀rẹ̀ sí Gbé Ilẹ̀ Israẹli
24Ọba Asiria kó àwọn eniyan láti Babiloni, Kuta, Afa, Hamati ati Sefafaimu, ó kó wọn dà sinu àwọn ìlú Samaria dípò àwọn ọmọ Israẹli tí ó kó lọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Samaria, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú rẹ̀. 25Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù OLUWA, nítorí náà OLUWA rán àwọn kinniun sí ààrin wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn eniyan tí ọba Asiria kó wá. 26Wọ́n bá lọ ròyìn fún ọba Asiria pé àwọn eniyan tí ó kó lọ sí ilẹ̀ Samaria kò mọ òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà, nítorí náà ni Ọlọrun ṣe rán kinniun tí ó ń pa wọ́n. 27Ọba bá pàṣẹ, ó ní, “Ẹ dá ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí a kó lẹ́rú pada sí Samaria, kí ó lè kọ́ àwọn eniyan náà ní òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà.” 28Nítorí náà, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí wọ́n kó wá láti Samaria pada lọ, ó sì ń gbé Bẹtẹli, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn eniyan náà bí wọn yóo ṣe máa sin OLUWA.
29Ṣugbọn àwọn oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí ń gbé Samaria ṣì ń gbẹ́ ère oriṣa wọn, wọ́n fi wọ́n sinu àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọmọ Israẹli ti kọ́. Olukuluku wọn ṣe oriṣa tirẹ̀ sí ibi tí ó ń gbé. 30Àwọn ará Babiloni gbẹ́ ère oriṣa Sukotu Benoti, àwọn ará Kuti gbẹ́ ère oriṣa Negali, àwọn ará Hamati gbẹ́ ère oriṣa Aṣima, 31àwọn ará Afa gbẹ́ ère oriṣa Nibihasi ati Tataki, àwọn ará Sefafaimu sì ń sun ọmọ wọn ninu iná fún Adirameleki ati Anameleki, àwọn oriṣa wọn. 32Àwọn eniyan náà bẹ̀rù OLUWA pẹlu, wọ́n sì yan oniruuru eniyan lára wọn, láti máa ṣe alufaa níbi àwọn pẹpẹ oriṣa gíga, láti máa bá wọn rúbọ níbẹ̀. 33Wọ́n ń sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n tún ń bọ àwọn oriṣa tí wọn ń bọ tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tí olukuluku wọ́n ti wá.
34Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe títí di òní olónìí. Wọn kò bẹ̀rù OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, tabi àṣẹ tí ó pa, tabi òfin tí ó ṣe fún àwọn ọmọ Jakọbu, tí ó sọ ní Israẹli.#Jẹn 32:28; 35:10 35OLUWA bá wọn dá majẹmu, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, wọn kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, tabi kí wọ́n júbà wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tabi kí wọ́n rúbọ sí wọn;#Eks 20:5; Diut 5:9 36ṣugbọn wọ́n gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti pẹlu ọwọ́ agbára ńlá ati ipá. Ó ní kí wọ́n máa tẹríba fún un, kí wọn sì máa rúbọ sí i.#Diut 6:13 37Ó ní wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, àṣẹ ati òfin tí ó kọ sílẹ̀ fún wọn mọ́. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa, 38wọn kò sì gbọdọ̀ gbàgbé majẹmu tí òun bá wọn dá. Wọn kò gbọdọ̀ bẹ̀rù àwọn oriṣa, 39ṣugbọn kí wọn bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wọn, yóo sì gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn. 40Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò gbọ́, wọ́n sì ń tẹ̀lé ìwà àtijọ́ wọn.
41Àwọn eniyan ilẹ̀ náà sin OLUWA, ṣugbọn wọ́n ń bọ àwọn ère tí wọ́n gbẹ́ pẹlu. Àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ wọn sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí di òní olónìí.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 17: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀