1
AISAYA 65:24
Yoruba Bible
Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn, kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí AISAYA 65:24
2
AISAYA 65:17
OLUWA ní, “Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun; a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́, tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn.
Ṣàwárí AISAYA 65:17
3
AISAYA 65:23
Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù, wọn kò ní bímọ fún jamba; nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́, àwọn ati àwọn ọmọ wọn.
Ṣàwárí AISAYA 65:23
4
AISAYA 65:22
Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé, wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ. Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò, àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Ṣàwárí AISAYA 65:22
5
AISAYA 65:20
Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́, àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún, a óo sọ pé ó kú ikú ègún.
Ṣàwárí AISAYA 65:20
6
AISAYA 65:25
Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri; kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù, erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára. Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ṣàwárí AISAYA 65:25
7
AISAYA 65:19
N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu, inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi. A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́, ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.
Ṣàwárí AISAYA 65:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò