AISAYA 65

65
Ìyà tí Ọlọrun yóo fi Jẹ Àwọn Ọlọ̀tẹ̀
1Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi,#Rom 10:20
ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi.
Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé,
“Èmi nìyí, èmi nìyí.”
2Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan;#Rom 10:21
àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára,
tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn,
3tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú,
níṣojú mi, nígbà gbogbo.
Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà,
wọ́n ń sun turari lórí bíríkì.
4Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú,
tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru;
àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,
tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́.
5Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí,
nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.”
Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi,
bí iná tí ó ń jó lojoojumọ.
6Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé,
“N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san.
7N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn,
ati ti àwọn baba wọn.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá,
wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké.
N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn.
8“Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà,
tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́,
nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’
bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi,
n kò ní pa gbogbo wọn run.
9N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu,
àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda.
Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀,
àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀.
10Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran,#Joṣ 7:24-26
àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí,
fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi.
11“Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀,
tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi,
tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire,
tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́.
12N óo fi yín fún ogun pa,
gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn;
nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn,
nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́,
ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi;
ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí.
13Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ,
ṣugbọn ebi yóo máa pa yín;
àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini,
ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín.
Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀,
ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín.
14Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn,
ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá;
ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn.
15Orúkọ tí ẹ óo fi sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi
yóo di ohun tí wọn yóo máa fi gégùn-ún.
Èmi Oluwa Ọlọrun óo pa yín.
Ṣugbọn n óo pe àwọn iranṣẹ mi ní orúkọ mìíràn.
16Dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ tọrọ ibukun ní ilẹ̀ náà,
yóo máa tọrọ rẹ̀ ní orúkọ Ọlọrun òtítọ́,
ẹnikẹ́ni tí yóo bá sì búra ní ilẹ̀ náà,
orúkọ Ọlọrun òtítọ́ ni yóo máa fi búra.
Àwọn ìṣòro àtijọ́ yóo ti di ohun ìgbàgbé,
a óo sì ti fi wọ́n pamọ́ kúrò níwájú mi.”
Ayé Tuntun
17OLUWA ní,#Ais 43:18; 66:22; Jer 3:16 2 Pet 3:13; Ifi 21:1
“Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun;
a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́,
tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn.
18Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí inú yín ó máa dùn,
kí ẹ sì máa yọ títí lae, ninu ohun tí mo dá.
Wò ó! Mo dá Jerusalẹmu ní ìlú aláyọ̀,
mo sì dá àwọn eniyan inú rẹ̀ ní onínú dídùn.
19N óo láyọ̀ ninu Jerusalẹmu,
inú mi óo sì máa dùn sí àwọn eniyan mi.
A kò ní gbọ́ igbe ẹkún ninu rẹ̀ mọ́,
ẹnikẹ́ni kò sì ní sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ninu rẹ̀ mọ́.#Ais 35:10; 62:5; Ifi 7:17; 21:4
20Ọmọ tuntun kò ní kú ní Jerusalẹmu mọ́,
àwọn àgbààgbà kò sì ní kú láìjẹ́ pé wọ́n darúgbó kùjọ́kùjọ́.
Kàkà bẹ́ẹ̀, ikú ọ̀dọ́ ni a óo máa pe ikú ẹni tí ó bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún.
Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá kú ní ẹni ọgọrun-un ọdún,
a óo sọ pé ó kú ikú ègún.
21Wọn óo kọ́ ilé, wọn óo gbé inú rẹ̀;
wọn óo gbin ọgbà àjàrà, wọn óo sì jẹ èso rẹ̀.
22Wọn kò ní kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé,
wọn kò sì ní gbin ọgbà àjàrà fún ẹlòmíràn jẹ.
Àwọn eniyan mi yóo pẹ́ láyé bí igi ìrókò,
àwọn àyànfẹ́ mi yóo sì jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
23Wọn kò ní ṣe iṣẹ́ àṣedànù,
wọn kò ní bímọ fún jamba;
nítorí ọmọ ẹni tí OLUWA bukun ni wọn yóo jẹ́,
àwọn ati àwọn ọmọ wọn.
24Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn,
kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.
25Ìkookò ati ọmọ aguntan yóo jọ máa jẹ káàkiri;#Ais 11:6-9
kinniun yóo máa jẹ koríko bíi mààlúù,
erùpẹ̀ ni ejò yóo máa jẹ, wọn kò ní máa panilára.
Wọn kò sì ní máa panirun lórí òkè mímọ́ mi mọ́.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 65: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀