ÌMỌ́MỌ́ TÍ Ó JỌRA

"Docudrama lórí ìgbésí-ayé Jésù Kristi, cinema “JESU” yí ni wọ́n ti ṣe ìtumọ̀ rẹ̀ sí àwọn ede tó lé ní ẹgbẹ̀rún-kan-àti-erínwó látìgbà ìfisóde rẹ̀ ní 1979. Ó jẹ́ àwòrán cinema tí a ti ṣe ìtumọ̀ rẹ̀ tí a sì wò nígbà tí ó pọ̀ jùlọ. Olùṣọ́-àgùntàn Rick Warren, òǹkọ̀wé tó kọ “The Purpose Driven Life,” ṣọpẹ́ “Cinema ‘JESU’ yìí ló jẹ́ ohun èlò ìhìnrere tó múná-dóko jùlọ tí àwọn ènìyàn ṣẹ̀dá.” Àwọn adarí ẹ̀sìn àti awọn olóye erínwó-léní-àádọ́ta ló ṣe àyẹ̀wọ̀ ìwé àfọwọ́kọ cinema náà láti ri dájú pé ó tẹ̀lé ìtàn àti òtítọ́ Bíbélì. Ìwé àfọwọ́kọ náà dá lórí Ìhìnrere Lúùkù, nítorí náà ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àwòrán cinema náà ló wà nínú Bíbélì. Àwọn ìgbìyànjú láti ṣe àfihàn àṣà àwọn ará Júù àti Róòmù láti bíi ọdún ẹgbẹ̀rún-méjì sẹ́yìn pẹ̀lú: aṣọ tí a fi ọwọ́ hun ní awọn àwọ̀ márùn-dín-lógójì tí wọ́n ń lò nígbà náà, àwọn ìkòkò tí a mọ pẹ̀lú àwọn ìlànà àtijọ́, àti yíyọ àwọn ọ̀pá tẹlifoonu òde-òní àti ti iná eletiriki kúrò ní àwọn ibi tí wọ́n ti ya àwòrán náà. Àwọn ọ̀nà igba ó lé ní méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti ya cinema náà ní ìlú Ísírẹ́lì l'ọ́dún 1979, pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Arabu. Nígbàkúùgbà tí ó ba ṣeé ṣe, wọ́n ya àwọn àwòrán nì ní àwọn ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn."