Luk 8

8
Àwọn Obinrin Tí Wọn Ń Ran Jesu Lọ́wọ́
1O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀.
2Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
3Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.
Òwe Afunrugbin
(Mat 13:1-9; Mak 4:1-9)
4Nigbati ọ̀pọ ijọ enia pejọ pọ̀, lati ilu gbogbo si tọ̀ ọ wá, o fi owe ba wọn sọ̀rọ pe:
5 Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ.
6 Omiran si bọ́ sori apata; bi o si ti hù jade, o gbẹ nitoriti kò ni irinlẹ omi.
7 Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa.
8 Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.
Ìdí Tí Jesu Fi Ń Lo Òwe
(Mat 13:10-17; Mak 4:10-12)
9Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si?
10O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.
Jesu Ṣe Àlàyé Òwe Nípa Afunrugbin
(Mat 13:18-23; Mak 4:13-20)
11Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun.
12 Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là.
13 Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin.
14 Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo.
15 Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.
Fìtílà Tí A Bò Mọ́lẹ̀
(Mak 4:21-25)
16 Kò si ẹnikẹni, nigbati o ba tàn fitilà tan, ti yio fi ohun elò bò o mọlẹ, tabi ti yio gbé e kà abẹ akete; bikoṣe ki o gbé e kà ori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọ̀ ile ki o le ri imọlẹ.
17 Nitori kò si ohun ti o lumọ́, ti a ki yio fi hàn, bẹ̃ni kò si ohun ti o pamọ́, ti a kì yio mọ̀, ti ki yio si yọ si gbangba.
18 Njẹ ki ẹnyin ki o mã kiyesara bi ẹnyin ti ngbọ́: nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a o fifun; ati ẹnikẹni ti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi ti o ṣebi on ni.
Ìyá ati Àwọn Arakunrin Jesu
(Mat 12:46-50; Mak 3:31-35)
19Nigbana ni iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia.
20Nwọn si wi fun u pe, Iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ri ọ.
21O si dahùn o si wi fun wọn pe, Iya mi ati awọn arakunrin mi li awọn wọnyi ti nwọn ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si nṣe e.
Jesu Mú Kí Ìgbì Dákẹ́ Rọ́rọ́
(Mat 8:23-27; Mak 4:35-41)
22O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ.
23Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu.
24Nwọn si tọ̀ ọ́ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si dá, idakẹ-rọrọ si de.
25O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.
Jesu Wo Wèrè Ará Geraseni Sàn
(Mat 8:28-34; Mak 5:1-20)
26Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili.
27Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji.
28Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró.
29(Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.)
30Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? Ó si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ.
31Nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe rán wọn lọ sinu ibu.
32Agbo ẹlẹdẹ pipọ si mbẹ nibẹ̀ ti njẹ li ori òke: nwọn si bẹ̀ ẹ ki o jẹ ki awọn wọ̀ inu wọn lọ. O si jọwọ wọn.
33Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi.
34Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na.
35Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn.
36Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada.
37Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin.
38Njẹ ọkunrin na ti ẹmi èṣu jade kuro lara rẹ̀, o bẹ̀ ẹ ki on ki o le ma bá a gbé: ṣugbọn Jesu rán a lọ, wipe,
39 Pada lọ ile rẹ, ki o si sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọ bi o ti pọ̀ to. O si lọ, o si nròhin já gbogbo ilu na bi Jesu ti ṣe ohun nla fun on to.
Ìtàn Ọmọbinrin Jairu ati Ti Obinrin Tí Ó Fọwọ́ Kan Aṣọ Jesu
(Mat 9:18-26; Mak 5:21-43)
40O si ṣe, nigbati Jesu pada lọ, awọn enia tẹwọgbà a: nitoriti gbogbo nwọn ti nreti rẹ̀.
41Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Jairu, ọkan ninu awọn olori sinagogu, o wá: o si wolẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá si ile on:
42Nitori o ni ọmọbinrin kanṣoṣo, ọmọ ìwọn ọdún mejila, o nkú lọ. Bi o si ti nlọ awọn enia nhá a li àye.
43Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá,
44O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ.
45Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi?
46Jesu si wipe, Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi: nitoriti emi mọ̀ pe aṣẹ jade lara mi.
47Nigbati obinrin na si mọ̀ pe on ko farasin, o warìri, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ fun u li oju awọn enia gbogbo nitori ohun ti o ṣe, ti on fi fi ọwọ́ tọ́ ọ, ati bi a ti mu on larada lojukanna.
48O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, tújuka: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia.
49Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, ẹnikan ti ile olori sinagogu wá, o wi fun u pe, Ọmọbinrin rẹ kú; má yọ olukọni lẹnu mọ.
50Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o da a li ohùn, wipe, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nikan ṣa, a o si mu u larada.
51Nigbati Jesu si wọ̀ ile, kò jẹ ki ẹnikẹni wọle, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati baba on iya ọmọbinrin na.
52Gbogbo nwọn si sọkun, nwọn pohùnrere ẹkún rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ má sọkun mọ́; kò kú, sisùn li o sùn.
53Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú.
54Nigbati o si sé gbogbo wọn mọ́ ode, o mu u li ọwọ́, o si wipe, Ọmọbinrin, dide.
55Ẹmí rẹ̀ si pada bọ̀, o si dide lọgan: o ni ki nwọn ki o fun u li onjẹ.
56Ẹnu si yà awọn õbi rẹ̀: ṣugbọn o kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe wi fun ẹnikan li ohun ti a ṣe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Luk 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa