Luk 17

17
Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ohun Ìkọsẹ̀
(Mat 18:6-7; Mak 9:42)
1O SI wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ko le ṣe ki ohun ikọsẹ̀ má de: ṣugbọn egbé ni fun ẹniti o ti ipasẹ rẹ̀ de.
2 Iba san fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si gbé e jù sinu okun, ju ki o mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi kọsẹ̀.
3 Ẹ mã kiyesara nyin: bi arakunrin rẹ ba ṣẹ̀, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari jì i.
Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀
(Mat 18:15,21-22)
4 Bi o ba si ṣẹ̀ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ̀ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari jì i.
Ọ̀rọ̀ Jesu Nípa Igbagbọ
(Mat 17:20)
5Awọn aposteli si wi fun Oluwa pe, Busi igbagbọ́ wa.
6Oluwa si wipe, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irugbin mustardi, ẹnyin o le wi fun igi sikamine yi pe, Ki a fà ọ tú, ki a si gbìn ọ sinu okun; yio si gbọ́ ti nyin.
Òwe Iṣẹ́ Ọmọ-Ọ̀dọ̀
7 Ṣugbọn tani ninu nyin, ti o li ọmọ-ọdọ, ti o ntulẹ, tabi ti o mbọ́ ẹran, ti yio wi fun u lojukanna ti o ba ti oko de pe, Lọ ijoko lati jẹun?
8 Ti kì yio kuku wi fun u pe, Pèse ohun ti emi o jẹ, si di amure, ki iwọ ki o mã ṣe iranṣẹ fun mi, titi emi o fi jẹ ti emi o si mu tan; lẹhinna ni iwọ o si jẹ, ti iwọ o si mu?
9 On o ha ma dupẹ lọwọ ọmọ-ọdọ na, nitoriti o ṣe ohun ti a palaṣẹ fun u bi? emi kò rò bẹ̃.
10 Gẹgẹ bẹ̃li ẹnyin pẹlu, nigbati ẹ ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun nyin tan, ẹ wipe, Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe.
Jesu Wo Àwọn Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn
11O si ṣe, bi o ti nlọ si Jerusalemu, o kọja larin Samaria on Galili.
12Bi o si ti nwọ̀ inu iletò kan lọ, awọn ọkunrin adẹtẹ̀ mẹwa pade rẹ̀, nwọn duro li òkere:
13Nwọn si nahùn soke, wipe, Jesu, Olukọni ṣãnu fun wa.
14Nigbati o ri wọn, o wi fun wọn pe, Ẹ lọ ifi ara nyin hàn fun awọn alufa. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, nwọn si di mimọ́.
15Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo.
16O si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o ndupẹ li ọwọ rẹ̀: ara Samaria ni on si iṣe.
17Jesu si dahùn wipe, Awọn mẹwa ki a ṣo di mimọ́? Awọn mẹsan iyokù ha dà?
18 A ko ri ẹnikan ti o pada wá fi ogo fun Ọlọrun, bikọse alejò yi?
19O si wi fun u pe, Dide, ki o si mã lọ: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada.
Bí Ìjọba Yóo Ti Ṣe Dé
(Mat 24:23-28,37-41)
20Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi:
21 Bẹ̃ni nwọn kì yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin.
22O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ọjọ mbọ̀, nigbati ẹnyin o fẹ lati ri ọkan ninu ọjọ Ọmọ-enia, ẹnyin kì yio si ri i.
23 Nwọn o si wi fun nyin pe, Wo o nihin; tabi wo o lọhun: ẹ má lọ, ẹ máṣe tẹle wọn.
24 Nitori gẹgẹ bi manamana ti ikọ li apakan labẹ ọrun, ti isi mọlẹ li apa keji labẹ ọrun: bẹ̃li Ọmọ-enia yio si ri li ọjọ rẹ̀.
25 Ṣugbọn kò le ṣaima kọ́ jìya ohun pipo, ki a si kọ̀ ọ lọdọ iran yi.
26 Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹ̃ni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia.
27 Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ̀ inu ọkọ̀ lọ, kíkun omi si de, o si run gbogbo wọn.
28 Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Loti; nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn nrà, nwọn ntà, nwọn ngbìn, nwọn nkọle;
29 Ṣugbọn li ọjọ na ti Loti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ̀ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn.
30 Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ-enia yio farahàn.
31 Li ọjọ na, eniti o ba wà lori ile, ti ẹrù rẹ̀ si mbẹ ni ile, ki o máṣe sọkalẹ lati wá kó o; ẹniti o ba si wà li oko, ki o máṣe pada sẹhin.
32 Ẹ ranti aya Loti.
33 Ẹnikẹni ti o ba nwá ati gbà ẹmi rẹ̀ là yio sọ ọ nù; ẹnikẹni ti o ba si sọ ọ nù yio gbà a là.
34 Mo wi fun nyin, li oru ọjọ na, enia meji yio wà lori akete kan; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.
35 Enia meji yio si ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.
36 Enia meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ.
37Nwọn si da a lohùn, nwọn bi i pe, Nibo, Oluwa? O si wi fun wọn pe, Nibiti okú ba gbé wà, nibẹ̀ pẹlu ni idì ikojọ pọ̀ si.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Luk 17: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa