ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌNÀpẹrẹ

ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌN

Ọjọ́ 1 nínú 7

ỌJỌ́ KIN-NI: ìyìn jẹ́ ìgbọràn

Ǹjẹ́ o ti lérò wípé ìgbèsí ayé rẹ kò ríbí o ti rò pé ó máa rí, bí ẹnipé o wà ní ojú kan tí ìrora sì yí ọ ka, ìkùnnà tàbí ìkóríta àṣeyọrí. Nígbà tí a bání irú ìrírí wọ̀nyí , a ó kígbe sí Ọlọ́run láti gbà wálọ́wọ́ ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń pe ní ‘’ àkókò aginjù’’ a rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lápapọ̀ nípasẹ̀ aginjù, fún ogójì ọdún láàrín ìjáde wọn láti Éjíbítì àti wíwọ inú ilẹ̀ ìlérí wọn ní Kénánì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn gbàgbọ́ wípé àkókò wọn ti kọjá.

Lẹ́yìn ogójì [40] ọdún tí wọ́n ti ń rìn kiri, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé bèbè àṣeyọrí wọn . Bi wọ́n ṣe dojukọ ilẹ̀ náà nìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín tí ó jẹ́ kí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí nímọ̀lára bí ìlérí tí kò ṣé é ṣe, wọ́n dojúkọ àwọn ìlú olódi. Bí ó bá ṣe ìwọ ni , o lè nírètí pé Ọlọrun yóò pèsè àwọn òmìrán ti yóò bá ọ wó odi náà lulẹ̀ tàbí kí ilẹ̀kùn náà ṣí tìyanutìyanu kí o leè rìn kọjá, ṣugbọ́n kò ríbẹ̀ẹ̀.

Dípò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fi ìlànà pàtàkì kan sílẹ̀ ‘’ Ẹ yí odi ìlú náà ká pẹ̀lú ipè júbélì ‘’ O leè wòye pé kín ni irinṣẹ́ ìyìn ní láti ṣe pẹ̀lú wíwọ inú ìlérí Ọlọ́run? Ó dára:

I. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àdìtú orin.

II. Ìyìn tako ọgbán ènìyàn, kì í ṣe ìgbésẹ̀ tí à n yàn nígbà tí a bá ń ní ìdojúkọ.

III. Òun ló n tọ ipa wa pẹ̀lú agbára ọlọ́run àti èto rẹ̀.

IV. Ó ń yí ojú wa kùrò níbi àìṣedéédé wa sí ti Ọ́lọ́run àìlópin.

V. Ìyìn jẹ́ ọ̀nà tí a gbà di òtítọ́ Ọlọ́run mú ṣinṣin àti ìjìyà rẹ̀ lórí ipò wa.

Nígbà tí ọlọ́run bá fún wa ní ìtọ́niìyin bí a ti ń dojúkọ ogun ayé, oun kan tí o yẹ kí ó jẹ́ ojúṣe wa ni ìgbọràn. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ísírẹ́lì ṣe tẹ̀lé ìtọni Ọlọ́run. Wọ́n yìn-ín pẹ̀lú ohùn wọn àti àwọn oun èlò orin, ó mú ki àwọn odi náà wó lulẹ̀.

Bákan náà, gbé ohùn rẹ sókè, gbé àwọn ohun èlò orin rẹ sókè, kí o sì gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ wípé ìṣẹgun ni tìrẹ.Bí o ti ń ṣe èyí, yóò wo àwọn ògiri ti ó dúró ní oju ọ̀nà ayé rẹ, yóò sì mú ọ wọ ìlérí Rẹ̀ lọ.

ÌRÍSÍ:

Àwọn odi wo ni ìwọ n dojúkọ lónìí? Báwo ni o ṣe leè lo orin ìyìn,láti fi ìgbọnran rẹ hàn sí Ọlọ́run?

ÀDÚRÀ:

Olúwa, rànmílọ́wọ́ láti tẹ̀le ìtọ́ni rẹ, kìn n sì paọ̀nàrẹ mọ́, nígbà tí ó bá dàbí ẹni pé kò yémi mo. Mo gbé oùn mi sókè fún ìyìn lóni, Ní ìgbàgbọ́ wípé oó wo odi ayé mi palẹ̀. Àmín

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ÀDÌTÚ ORIN ÌYÌN

Àwọn ohun ìjinlẹ ti Ìyin: Nínú ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ méje yìí, Dúnsìn Oyèkan ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àdìtú inú orin ìyìn gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà àwọn onígbàgbọ́. Bi o ṣe kàá, ìwé májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun sì yànnànáa rẹ̀. Gbìyànjú láti lo àwọn oun ìjà ti ẹ̀míi nì, ní àkókò ayọ ju àkókò ìpèníjà lọ.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Integrity Music fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: dunsinoyekan.com