ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUNÀpẹrẹ
Níní òye Ìgbàgbọ́
Hébérù 11:1 tú mọ̀ ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdánilójú àwọn ohun tí à ń retí, ìmọ̀ tó dájú lórí ohun tí a kò rí. Ìgbàgbọ́ jẹ́ ohun èlò ìpìlẹ̀ nínú ìrìn wa pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́. Yóò nira púpọ̀ láti ní ìrìn tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run láì sí ìgbàgbọ́. A ò le rí Ọlọ́run ní ojúkojú, ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ àti ìsìn pẹ̀lú Ọlọ́run máa ń ṣeé ṣe pẹ̀lú agbára ìgbàgbọ́. Gbogbo ìwé Hébérù 11 pín ìbùkún ìgbàgbọ́ àti bí àwọn baba ṣe rìn ní àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.
Hébérù 11 ẹsẹ 6 fi yé wa pé láì sí ìgbàgbọ́, a kò le wu Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ nìkan ni a lè fi wu Ọlọ́run. Ìbáṣepọ̀ wá pẹ̀lú Ọlọ́run dá lórí ìmọ̀ wa tí a ní nípa rẹ̀ kìí ṣe pé nítorí a lè ríi lójú kojú. Nítorí náà ẹsẹ Bíbélì náà tẹ̀síwájú láti sọ pé ẹnikẹ́ni tí yóò bá tọ Ọlọ́run lọ gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé òun ni. Èyí ni pé o gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà. Èyí nìkan ni ọ̀nà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ ní bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ àti gbígba àdúrà. Òye yìí ṣe pàtàkì láti ní nítorí a kò le rí Ọlọ́run lójú kojú pẹ̀lú ojú lásán ṣùgbọ́n a lè ríi pẹ̀lú ọkàn àti ẹ̀mí wá. Ọgbọ́n àti òye wa kò lè ṣe àkàwé èyí rárá.
Fún àpẹẹrẹ, ní ẹsẹ 4, Ábẹ́lì ò rí Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó rú ẹbọ tó dára jù ti arákùnrin rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ó lè pinnu láti rú ẹbọ kan ṣá ṣùgbọ́n Ábẹ́lì yàn láti rú ẹbọ tó dára sí Ọlọ́run. Ó ní ìgbàgbọ́ tó jìnlẹ̀ pé Ọlọ́run kan wà lókè ti ohun tó dára yẹ fún. Ní ẹsẹ 7, Nóà pèsè ọkọ̀ láti gba ẹnikẹ́ni tó fẹ́ láti gbọ́ kúrò lọ́wọ́ ewu ẹ̀kún omi. Nóà ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run fún un ní ohun tó yẹ láti ṣe. Àkọ́kọ́, nítorí ó gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run pé ẹ̀kún omi ń bọ̀, ó tún gbàgbọ́ pé ọkọ̀ yìí ni oore - ọ̀fẹ́ tí yóò gbà òun là kúrò nínú ewu ẹ̀kún omi yìí.
Ní ẹsẹ 8, Ábúráhámù ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé kí ó lọ sí ibi tí òun ó fihàn án. Ìgbàgbọ́ ni yóò gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí yóò fi dìde lọ sí ìrìn àjò ibi tí kò mọ láì sí òye tàbí ìtọ́sọ́na kan rí. Ó gbé ìgbésẹ̀ náà pẹ̀lú ìmọ̀ pé Ọlọ́run yóò máa tọ́ òun bí òun ṣe ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ yìí.
Àwọn baba yìí àti àwọn àpẹẹrẹ mìíràn ti fi ìgbé ayé ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú gíga àti ìṣòótọ́ Ọlọ́run hàn. Èyí ni ọ̀nà tó dára jù láti wu Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìrìn-àjò Kristẹni jẹ́ èyí tí a kò ti rí Ọlọ́run lójú-kojú, a máa ń bá A ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti wu Ọlọ́run nínú ìrìn wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ìgbàgbọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kò lè rí I pẹ̀lú ojú wa nípa tara. À ń gbọ́ Ọ nípa ìgbàgbọ́, à ń bá A sọ̀rọ̀ nípa Ìgbàgbọ́, a sì ń tọ̀ Ọ́ lọ nínú àdúrà nípa ìgbàgbọ́.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo:https://mountzionfilm.org/