EbiÀpẹrẹ

Ebi

Ọjọ́ 4 nínú 4

Ebi Gẹ́gẹ́ bí Òpó-pàtàkì fún Ìgbàgbọ́ Wa

Ó dá mi lójú pé o lè dárúkọ àwọn tí o máa ń retí láti lo àkókò pẹ̀lú. Kò yẹ kí á nìkàn ṣe ayé. Ìṣẹ̀dá wa jẹ́ alásopọ̀, nítorí pé a dá wan ní àwòrán Ọlọ́run alábàáṣepọ̀. Èrò pàtàkì Ọlọ́run fún dídá w ani ìdàpọ̀. Ó fẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, kí á dàbí Rẹ̀, kí á sì fi ògo Rẹ̀ hàn fún ayé. Lóòótọ́ ni ìṣubú ènìyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀ ba ìdàpọ̀ pípé tí Ọlọ́run pète pé kí á gbádùn pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ní ètò kan nílẹ̀: Jesu.

Ó ṣe é ṣe kí o ní ìtàn láti sọ nipa àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ará ẹbí rẹ tí wọ́n ti wá láti mọ Jésù tí ayé wọn sì ti yípadà gan-an pẹ̀lú ìfẹ́ láti lo àsìkò pẹ̀lú Ọlọ́run. Wà á tin í ìrírí èyí pẹ̀lú. Ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni èsì ọ̀ranyàn ti ènìyàn tí ó ń pòǹgbẹ fún púpọ̀ Ọlọ́run sí i. ní ọ̀nà mìíràn ẹ̀wẹ̀: ebi wa fún ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run – lílo àsìkò nínú àdúrà, ìjọ́sìn, àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ – jẹ́ láríjà ìgbàgbọ́ wa. Dafidi ṣe àlàyé rẹ̀ báyìí: ‘Ohun kan nim o ti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa, ohun náà ni emi ó máa wá kiri: kí èmi kí ó le máa gbé inú ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí emi kí ó le máa wo ẹwa Olúwa, kí emi kí ó sì máa fi inú dídùn wo tẹmpili Rẹ̀.’ (Orin Dafidi 27:4)

Gbogbo ènìyàn ni ó ní àdámọ́ ebi fún oúnjẹ nítorí tí ó pèsè ìgbéró àti èròjà-aṣaralóore tí ó máa ń mú kí ará dá. Nípa ti ẹ̀mí, a ní nínú wa, àdámọ́ ebi fún Ọlọ́run, èyí tí lílo àsìkò tó pọ̀ nínú àdúrà àti ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń tẹ́ lọ́rùn. Dafidi gbé ìgbésíayé rẹ̀ fún Ọlọ́run pátápátá. Ìtara rẹ̀ ọlọ́kàn-kan-ṣoṣo ni ìdí tí a fi ṣe àpéjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ẹni bí ọkàn Ọlọ́run. Ro ipa tí ayé wa kì bá ní bí a bá ní irúfẹ̀ ìtara yìí tí a rí nínú ayé Dafidi yìí fún Ọlọ́run. Ro bí a ṣè lè yí ayé àyíká wa padà bí a bá koná mọ́ ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run, tí à ń paná ìṣìnà tí a sì ń gbájú mọ́ Jesu nìkan.

Gẹ́gẹ́ bí Luku 10 ṣe sọ ìtàn arábìnrin méjì, Mary àti Martha, tí wọ́n ń gba Jesu ní àlejò ní ilé wọn. Mary jókòó kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́sẹ̀ Jesu nígbà tí Martha gbájú mọ́ rírí sí àìní Jesu nipa tara. Jesu sọ pé, ‘Martha, Martha, ò ń ṣe àníyàn ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ohun díẹ̀ ló nílò – tàbí ohun kan ṣoṣo. Mary ti yan ohun tí ó dára jù, a kò sì ní í gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.’ Kì í ṣe pé Jesu ń bá Martha wí tó bí ó ṣe ń pè é sí iwájú rẹ̀. Ó ń pe ìwọ pẹ̀lú. Wà á mọ ìdàgbà ebi láti mọ Ọlọ́run sí i tímọ́tímọ́. Wà á ní ìmisí láti wá àsìkò fún wíwà pẹ̀lú Ọlọ́run, àti pé kí Ó yí ọ padà, síwájú sí i àti síwájú si i, sí ìrí Rẹ̀, kí àwọn mìíràn lè máa bẹ̀rẹ̀ láti máa pòǹgbẹ fún Ọ pẹ̀lú.

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Ebi

Ìlànà kíkà yìí ṣe àwàjinlẹ̀ bí ebi wa láti mọ Ọlọ́run kí á sì sọ ọ́ di mímọ̀ máa ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ sínú èrèdí rẹ̀ fún ayé wa. Ṣe àwárí ohun tí ó sọ Dafidi di ẹni bí ọkàn Ọlọ́run – àti bí ìwọ pẹ̀lú ṣe lè gbé ayé pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn-kan fún Ọlọ́run, gbígbádùn ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jesu àti gbígbẹ́kẹ̀le láti tẹ́ àìní rẹ larùn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Lawrence Oyor fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.youtube.com/lawrenceoyor