Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ ÌsìnÀpẹrẹ

Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ Ìsìn

Ọjọ́ 1 nínú 7

Fi Ará Rẹ Fún

Ìgbé Àyè Kristeni jẹ "ìpè" sí irin-ajo ìgbé ayé ìrúbọ, ojẹ irin àjò ni ìwò pé òlè rìn díẹ̀ kó loti pari.

Irin àjò yì nilo gbogbo iṣẹdá rẹ láti rin; Àrà, Ọkan ati Ẹ̀mi. Òpè fún iyanda pátápátá, ifọkansin, ati iyasọtọ, o lè fà ohun kóhun sẹyìn.

"Fífi àrà rẹ" kii ṣe fún itẹlọrun ayé ẹṣẹ ati idibajẹ lati lè tẹ wọn lọrùn tàbí lati bá oṣuwọn wọn dọgba, rárá! O jẹ iyọnda àrà ẹni pátápátá fún Ọlọrun kó lè mọọ, kun inú rẹ láti bá ìfẹ pípé Rẹ mú.

Jésù daun ibeere nipa ofin to gajulọ pé; fẹràn Olùwà Ọlọrun rẹ pẹlú 'gbogbo' àyà rẹ, pẹlú 'gbogbo Ọkan rẹ àti pẹlú 'gbogbo' inú rẹ. Kiyesii ọrọ nà "gbogbo" eyi túmọ sí pé Ọlọrun pé fún ohun gbogbo to jẹ.

Sibẹ̀, gbogbo ìmọmọṣe ni o gbọdọ fi rìn irin-ajo nà pẹlu ìpinu lati sọ ọkan rẹ dọtun láì mú òhún kóhun sẹyìn.

Kika siwaju: Matteu 22:37, Deuteronomi 6:5

Adura: OLÙWÀ, ran mi lọwọ láti fi àrà mi fun Ọ pátápátá.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ìgbé Àyè Kristeni, Ìgbé Ayé Ìrúbọ Àti iṣẹ Ìsìn

Igbe Ayé Kristeni kii ṣe ìgbé Ayé irọrun, ọrọ àti itẹlọrun ní gbogbo ìgbà ṣugbọn ojẹ ìgbé Ayé Ìrúbọ ati ìsìn. Jésù wá sí ayé láti wá fi àpẹẹrẹ náà hàn fún wa láti ri. Jésù wá, o gbè ìgbé Ayé isẹrà ẹni, aimọtàrà ẹni nikan, iyasọtọ, iwọntunwọnsi ati ìrúbọ titi ti O fi kù fún ìràpadà wá. Ìdí yii ni àfi ni àkọsílẹ̀ rẹ ninú awọn ìwé ìhìnrere.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Adeoye Gideon fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL