Ibi Tí Àdúrà Ti Ń DájúÀpẹrẹ

Ọjọ́ Kẹrin
Gbígba Àdúrà Ní Ìgbà Tí Kò Sí Ìdálẹ́bi
Ní ìgbà tí a bá ti mọ̀ pé a ti dáríjì wá, ìmọ̀ ìyàlẹ́nu òmìnira kan máa ń gbéra sọ nínú ọkàn wa. A máa ń ní ìmọ̀lára pé a wà láàyè àti pé a ní òmìnira. Ṣùgbọ́n ó rọrùn láti kúrò ní ipò yẹn ki a si ṣe àwárí oríṣi ìgbèkùn tuntun òmíràn. Ọ̀pọ̀ nínú wa máa ń ṣe àwárí ẹ̀ pé pẹ̀lú pé a gbàgbọ́ pé Ọlọ́run dáríjì wa, a ń rò pé Ó ní ìbànújẹ́ ọkàn nítorí tiwa. Lẹ́ẹ̀kan síi, ìdálẹ́bi àti ìtìjú á gbéra sọ nínú ọkàn wa, a yíò sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ẹ̀rù àti àníyàn ja ìjàkadì pẹ̀lú bí a ṣe ń gbìyànjú láti jẹ́ olóòtítọ́.
Ibí yìí gan-an ni a ti nílò láti gbọ́ Róòmù 8:1: “Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsìnyí fún àwọn tí ó wà nínú Kristi Jésù.” Kò sí ìdálẹ́bi. Bí níní ìmọ̀ ìdáríjì bá yọrí sí òmìnira, mélòó mélòó ni bí a bá mọ̀ pé kò sí ìdálẹ́bi mọ́? Ṣùgbọ́n òmìnira tí èyí já sí fún wa yàtọ̀ sí ti ayé. Èyí kìí ṣe òmìnira láti lọ máa ṣe ohunkóhun tí a bá fẹ́. Èyí kìí ṣe òmìnira aláìlòfin. Òmìnira tí ó tọ́ wa láti jẹ́ olóòtítọ́ ni.
Mo ròó pé kò sí ẹnìkan ní ara wa tí ó gbìyànjú láti ṣe àìṣòtítọ́ nínú awọn àdúrà wa, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àdúrà wa lè jẹ́ kìkì àìṣòdodo. A mọ ẹ̀ṣẹ̀ wa, ìṣọ̀tẹ̀ wa, ìdibàjẹ́ wa ati Iàálàá wa, a kìí mẹ́nu ba, ṣùgbọ́n a ó kàn béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run kí Ó mú un kúrò tàbí kí Ó ṣe àtúnṣe ẹ̀. Ní ìgbà tí a bá rí ẹ̀ṣẹ̀ wa, a máa ń fi ìtara tọrọ àforíjì, pẹ̀lú ìrètí pé bí Ọlọ́run bá rí i pé tinútinú ni a fi tọrọ, bóyá Ó lè gba ẹ̀bẹ̀ wa. A gbàgbé pé kò sí ìdálẹ́bi mọ́ nísìnyí fún àwọn tí ó wà nínú Kírísítì Jésù, dípò kí a gbà bẹ́ẹ̀ kí a sì mú òtítọ́ nípa ara wa wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, a fi ara pa mọ́ kúrò fún dídán ojú Rẹ̀ nípa dídá ara wa ní ẹ̀bi.
Ọ̀nà kan ṣoṣo láti gbàgbọ́ ní tòótọ́ - délẹ̀ délẹ̀ - pé kò sí ìdálẹ́bi nínú Krísítì Jésù, ni láti mú ohun gbogbo tí ó jẹ́ kí a ní ìdálẹ́bi ní ìwájú Rẹ̀ kí a sì fií lélẹ̀ ní ẹsẹ̀ Rẹ̀. A kò lè fi ẹnu lásán jẹ́rìí sí òtítọ́ bí irú èyí, a nílò láti dán wọn wò. A nílò láti dán wò bóyá ní tòótọ́ ni a gbàgbọ́ pé ìgbàlà wà nípa ìgbàgbọ́ nìkan ṣoṣo nínú Kírísítì nìkan. A nílò láti dan wò bóyá kò sí ìdálẹ́bi. A ń dan wò bóyá a gba àwọn nǹkan wọ̀nyí gbọ́ nípa gbígbé gbogbo ara wa wá fún Ọlọ́run.
Níbo ni o ti ń tiraka láti mú òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Kí ni ó ṣòro fún ọ láti gbàgbọ́ pé Ọlọ́run lè gbà ní ọwọ́ ẹ? Ṣe ìbínú rẹ ni, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìlara àbí bóyá èrò jíjẹ́ aláìmọ́, ìdálẹ́bi tàbí ìbẹ̀rù? Báwo ni ó ṣe máa rí láti ríi pé Jésù ń gba àdúrà fún ọ, kì í ṣe ní ìgbà kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n ní lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí bí o ṣe ń la àwọn nǹkan wọ̀nyí kọjá?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àdúrà ní ìgbà míràn lè dà bíi ẹni wípé o dá nìkan wà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú àdúrà, mo gbìyànjú láti mú ẹ̀mí àti ọkàn mi dákẹ́, èrò inú mi sì ń sáré káàkiri. Ní ìgbà míràn mo kàn ma sùn lọ. Àwọn ìgbà kan wà tí ó dà bíi wípé àdúrà mi máa ń ta ba òrùlé padà. Àmọ́ ohun tí a kìí sábà mọ̀ ni wípé Olúwa n fún wa ní ìròyìn rere ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí á lo àkókò díẹ̀ láti gbé ìhìn rere nípa àdúrà yẹ̀ wò.
More