Ibi Tí Àdúrà Ti Ń DájúÀpẹrẹ

Ọjọ́ Kejì
Ọlọ́run Ń Ṣe Ju Bí A Ti Ní Ní Èrò Lọ
Ìṣòro tí ó wà pẹ̀lú àdúrà ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ wa nípa ohun tí àdúrà jẹ́, àwọn ohun rere tí a kọ́ ní ilé ìjọsìn, àwọn ẹ̀kọ́ nípa àdúrà, àti ní ìgbà tí àwa fúnraa wa bá ń gba àdúrà pàápàá, kì í fi bẹ́ẹ̀ tù wá nínú ní inú àwọn ìjàkadì wa. Ó rọrùn láti gbàgbé òtítọ́ ní ìgbà tí àdúrà bá nira. A gba ohùn gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láti gbà wá là, síbẹ̀ nínú àdúrà a gbàgbé ohun tí Ó ti ṣe, a sì gbà pé ohun tí Ó fẹ́ ni pé kí á máa hùwà rere, kí a sì máa ṣe ohun tí ó tọ́. A nílò ju àwọn ohun ìrántí rere lọ níhìn-ín – a nílò àwọn ìtọ́ni fún gbígbé nínú òtítọ́.
A ti rí i pé apá kan ní ára ìhìn rere nípa àdúrà ni wípé Ọlọ́run ń bá wa pàdé nínú òtítọ́ nípa rírán wa ní étí pé a kò mọ bí a ṣe ń gba àdúrà. A lè mí èémí gígùn sí inú, kí á sì mí kanlẹ̀ dòò. Ọlọ́run mọ̀. Ó yé Ọlọ́run. A ti lẹ̀ lè sọ wípé Ó ti fún wa ní àlùfáà àgbà nínú Jésù tí ó mú wa tọ Baba lọ, nítorí náà a kò nìkan dúró ní iwájú Rẹ̀, ṣùgbọ́n a ra àgà bò wa mọ́lẹ̀ a sì gbé wa ní ọwọ́ Ẹni tí Ó jẹ́ pé nípa ìwàláàyè, ikú àti àjíǹde Rẹ̀ a gba ìwàálàyè Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún ṣe ju èyí lọ.
Ní ìgbà tí mo bá ń tiraka nínú àdúrà, mo ṣe àwàrí pé bí mo ti lẹ̀ mọ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí, bí mo ti lẹ̀ lè fi ìdí onírúurú ohun rere nípa àdúrà mú'lẹ̀, ó sáábà máa ń ṣe mí bíi ẹni pé èmi nìkan ní mò ń ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Àdúrà jẹ́ iṣẹ́ tí mò ń ṣe. Bóyá ní ojú tìrẹ, èyí pàápàá kò rọrùn. Ó lè jẹ́ pé ohun tí ó yẹ kí o máa ṣe ni pé kí o máa gba àdúrà, ṣùgbọ́n o kìí ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà ní ibí, mo wo òye pé a ti rí ìṣòro wa. Ní ìgbà tí àdúrà bá jẹ́ ohun kan tí a rò pé ó yẹ kí a ṣe, tàbí ìgbòkègbodò kan tí ó yẹ kí a dá sílẹ̀, a tètè maá ń rí i pé kì í ṣe ohun tí a máa ń ṣe. Ṣùgbọ́n ká ní mo sọ fún ọ pé kì í ṣe ohun tí àdúrà túmọ̀ sí ní èyí ńkọ́? Ká ní mo sọ fún ọ pé àdúrà jẹ́ ohun tí ó yẹ kí o wọ inú rẹ̀ lọ ńkọ́? Ọ̀kan ní ara ohun tí ó dára nípa àdúrà ni pé kí o tó sọ ọ̀rọ̀ kan, Ọlọ́run ti pè ọ́ pé kí o wá sí inú ohun kan tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ nítorí ire rẹ. Kódà nínú ìtiraka láti wá àkókò láti gba àdúrà, Ọlọ́run máa ń ràn wá l'ọ́wọ́ nínú àìlera wa.
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn àná, Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé a ti rán Ẹ̀mí Mímọ́ sí inú ọkàn wa. Ní ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti polongo pé, "Ẹ̀mí tìkaara rẹ̀ ń bẹ̀bẹ̀ fún wa pẹ̀lú ìkérora tí a kò lè fi ẹnu sọ". Ẹ̀mí ń bẹ̀bẹ̀ fún wa láti inú ọkàn wa wá. Ẹ̀mí rí gbogbo ibi tí o ń sa ipá láti bójú tó. Ẹ̀mí mọ ìrora rẹ tí ó jinlẹ̀ jù, ìròbìnújẹ́ àti àìnírètí rẹ. Ẹ̀mí kò wo àwọn nǹkan wọ̀nyí láti òkèèrè, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí ti sọ̀kalẹ̀ wá sí inú àwọn ibi wọ̀nyí, Ó sì mọ̀ wọ́n ju bí a ṣe mọ̀ wọ́n lọ. Ẹ̀mí wà pẹ̀lú rẹ nínú ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ tí ó jinlẹ̀ jù.
A sọ ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ nípa Ọmọ. Ọmọ náà "wà láàyè ní ìgbà gbogbo láti sìpẹ̀" fún wa ní iwájú Bàbá. Kí a tó sọ ọ̀rọ̀ kan nínú àdúrà, Ẹ̀mí ń ké ìrora fún wa láti inú ọkàn wa, Ọmọ sì dúró ní iwájú Baba fún wa, Ó ń gba àdúrà fún wa. A gbé ọ̀rọ̀ tiwa mì nínú tiwọn. A ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àdúrà wa nípasẹ̀ tiwọn. Ní ìgbà tí a bá ń gba àdúrà, à ń wọ inú ìṣìpẹ̀ ti Ọmọ àti Ẹ̀mí fún wa, bí àdúrà wa ṣe ń gun òkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba.
Báwo ni ìṣìpẹ̀ Ọmọ àti Ẹ̀mí ṣe ń yí bí o ṣe ń gba àdúrà padà? Bí Ọlọ́run bá ti gba àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń bà ọ́ l'ẹ́rù ní àdúrà, bí Baba bá ti mọ gbogbo ohun tí a nílò kí a tóó bèèrè (Mátíù 6:8), kíni ó dé tí a fi ń tiraka láti gbé àwọn àníyàn wá fún Un? Báwo ni ó ṣe máa rí bí a bá kàn "fi ara wa hàn" (Róòmù 6:13) fún Ọlọ́run, ní ìfọkàntán iṣẹ́ Rẹ̀, tí a sì tún fi ọkàn tán An pé àdúrà Rẹ̀ tó?
Nípa Ìpèsè yìí

Àdúrà ní ìgbà míràn lè dà bíi ẹni wípé o dá nìkan wà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú àdúrà, mo gbìyànjú láti mú ẹ̀mí àti ọkàn mi dákẹ́, èrò inú mi sì ń sáré káàkiri. Ní ìgbà míràn mo kàn ma sùn lọ. Àwọn ìgbà kan wà tí ó dà bíi wípé àdúrà mi máa ń ta ba òrùlé padà. Àmọ́ ohun tí a kìí sábà mọ̀ ni wípé Olúwa n fún wa ní ìròyìn rere ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí á lo àkókò díẹ̀ láti gbé ìhìn rere nípa àdúrà yẹ̀ wò.
More