Mọ Ohùn Ọlọ́run // Kọ́ L'áti Pàdé Rẹ̀Àpẹrẹ

Recognizing God's Voice // Learn to Encounter Him

Ọjọ́ 4 nínú 4

Bí o ṣe lè jẹ́ Aláìní Ìbẹ̀rù (ní Àárín Ìrora rẹ)

Ẹ̀mí mímọ́ nínú wa, èyí ni ohun tí a gbọ́ lọ́dọ̀ Rẹ:

Mo mọ̀ wí pé ohun tí a sọ lẹ l'áti gbọ́. Mo mọ̀ wí pé ó kan ọ́ ní ọkàn ní ìgbà tí o gbọ́. Mo ti jẹ́ kí ọkàn rẹ rọ̀. Tí ó bá dùn ó, ní ìgbà tí o bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ líle, ìyẹn kìí ṣe nkan búburú. Ó fi hàn wí pé ọkàn rẹ kò le; ó fi hàn wí pé o ti jẹ́ kí n wọlé; ó fi hàn wí pé o ti jẹ́ kí n dúró.

Jẹ́ kí n dúró.

Sùgbọ́n kíni síṣe nípa ìrora yẹn? Kíni síṣe ní ìgbà tí ipò náà bá jẹ́ bákan náà, ní ìgbà dé ìgbà? Kíni síṣe ní ìgbà tí ó dàbí wí pé kò sí nkan tí ó dára síi, ní ìgbà tí o bá ní ìdánilójú wí pé ọ̀nà ti dí àti wí pé títán igun náà dàbíi wí pé kì yíò wà rárá? "Kíni báyìí?" ní ò ń sọ. "Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ sí'wájú?" ò n bẹ̀bẹ̀.

Mo mọ̀ wí pé o ní ìbànújẹ́. O fẹ́ àtúnṣe sí ipò náà—àti wí pé ó dára l'áti wá sí ọ̀dọ̀ mi, l'áti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ l'ọ́wọ́ mi. Ṣùgbọ́n gbọ́ ní báyìí, ọmọ. Ní ìgbà tí ìrora bá dé, o ní láti dì mí mú. Rántí wí pé o kò ní láti lọ sí iwájú, sí inú àgbègbè àìmọ̀, l'áì mọ ọ̀nà tí o lè yí sí.

Yí. Yí, ọmọ mi. Mo wà ní'bí.

Yí. Yí, ọmọ mi. Mo wà ní'bí.

Mo ní ìfẹ́ rẹ, o mọ̀. Àti wí pé ìfẹ́ náà ni yíò ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti pa ojú rẹ mọ́ sí ọ̀dọ̀ mi. Ó lè máà sí ìdáhùn tí ó rọ'rùn ní'bí—ṣé o lè fi ojú inú wòó? Ó le máà sí ìyípadà ójijì nínú ipò yìí . . . èyí sì lè jẹ́ ohun tí ó dára.

Ṣé o fi ara mọ́-ọn?

Má bínú wí pé ó dùn ọ́. Ṣùgbọ́n mò ń tọ́jú ọkàn rẹ. Jẹ́ kí n tọ́jú ọkàn rẹ. Fún mi ní èyí. Má sọ ara rẹ̀ sí ìrònú ní'pa ohun tí ìwo yíò ṣe ní'pa eni yìí ṣùgbọ́n gbé ojú rẹ sí ibi tí mo wà ní àkókò tí ìjà náà bá tún ti ṣẹlẹ̀. Ṣe àdáṣe wíwá mi ní ìgbà tí o bá tún bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan si. Ṣe é ní àkókò náà, kìí ṣe l'ẹ́yìn náà. Ṣe àdáṣe gbígbọ́ ohùn mi ní ìgbà tí ìwọ kò bá mọ ohun tí o ó sọ. Ṣe é ní àkókò tí o bá tún d'ojú kọ ọ́. Èmi wà pẹ̀lú rẹ, Ẹ̀mí Mímọ́ nínú rẹ̀.

Mo ní ìfẹ́ rẹ, aláìní ìbẹ̀rù.

Isẹ́ Àkànṣe:

Báwo ni a ṣe lè tẹ̀ sí'wájú? Ní gbà tí ó bá n dùn ọ́? Ní ìgbà tí àríyànjiyàn bá dàbí wí pé ó tóbi ju àríyànjiyàn lọ . . . Ní ìgbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ wá. . . Ní ìgbà tí a ti sọ àwọn nkan tí a kò l'érò l'áti sọ . . . tàbí ohun tí a fẹ́ sọ, ṣùgbọ́n a k'ábàámọ̀ . . . Ní ìgbà tí àwọn ọ̀rọ̀ ti ṣe ìpalára . . . Ní ìgbà tí a bá n gb'ìyànjú l'áti dáríjì . . . dáríji ara wa tàbí elòmíràn.

Báwo ni a ṣe fẹ́ mọ ohun tí ó kàn l'áti ṣe . . . ohun tí a ó sọ?

Báwo ni a ṣe fẹ́ dúró nínú ìbásọ̀rẹ́—àti rí ìfẹ́ àti ìgboyà l'áti ní ìfẹ́—ní ìgbà tí a bá ní ìbànújẹ . . . ìrẹ̀wẹ̀sì . . . ìbẹ̀rù ní'pa ohun tí ó lè wá?

ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìbéèrè tí ó dára . . . ìbéèrè pàtàkì. Ṣùgbọ́n ìbéèrè tí ó tóbi jù lọ ni wí pé: Báwo ni a ṣe lè má jẹ́ kí ọkàn wá le? Ní ìtorí wí pé ó rọ'rùn gaan l'áti lọ sí ipò ìwàláàyè lásán, l'áti ṣe àkóso àti dáàbòbo ara wa, l'áti pa ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ìpalára, l'áti pa wọ́n mọ́ kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Ṣùgbọ́n, nísìsiyìí, ni àkókò tí a ní'lò Rẹ̀ jù.

Ẹ jẹ́ kí á yí sí iha Ọlọ́run, ní báyìí. L'ápapọ̀, ẹ jẹ́ kí a gbẹ́kẹ̀lé oore Rẹ̀, ipá Rẹ̀, agbára Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ l'áti dásí wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣí ọkàn wa kí a bèèrè l'ọ́wọ́ Rẹ kí Ó dá ààbò bò wọ́n, dí'pò kí á gb'ìyànjú l'áti ṣe é fún ara wa. Àti wí pé ẹ jẹ́ kí a fún-Un ní ipò yìí. Tú pátápátá sí'lẹ̀ fún-Un—gbogbo ìrora, gbogbo ìbànújẹ́; gbogbo rúdurùdu, gbogbo ìpalára.

Gbé e lé l'ọ́wọ́. Kí o sì dúró. Dúró de ìdáhùn Rẹ̀. Máa ṣọ́ra kí o sì gbọ́ ohun tí Jésù ṣe. Ní'torí wí pé ìdáhùn Rẹ̀ jẹ́ ohun tí à ń dúró dè. Ó jẹ́ ohun tí a ní'lò ní báyìí.

Jésù, mo fẹ́ Ọ. Mo gbẹ́kẹ̀lé Ọ. O ní agbára l'áti k'ojú ìrora yìí. O jẹ́ onínnúre. Ọlọ́gbọ́n ni Ọ́, O sì dára. O ní ìfẹ́ mi. O mọ̀ mí dáradára ju bí mo ti mọ ara mi lọ. O fẹ́ ohun tí ó dára jù lọ fún mi. Ní itorí náà, mo gbẹ́kẹ̀lé Ọ. Mo gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìdáhùn Rẹ. Mo gbẹ́kẹ̀lé Ọ̀nà Rẹ. Mo fẹ́ to ẹtì síi. Ní'torí náà, ràn mí l'ọ́wọ́ l'áti rí Ọ, ràn mí l'ọ́wọ́ l'áti rí Ọ̀nà Rẹ, kí o sì ràn mí l'ọ́wọ́ l'áti mú kí ọkàn mi ṣí sí'lẹ̀ . . .

Ní ìrírí àdáro-ẹsẹ Rush—kí o sì bá Ẹ̀mí Mímọ́ pàdé ní ìgbésí ayé òde òni tìrẹ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Recognizing God's Voice // Learn to Encounter Him

Ohùn Ọlọ́run lè wá bíi ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tàbí ìró ìjì líle. Ohun gbòógì ni l'áti dá a mọ̀, bí ó ti wù kí ó wá—àti kí a gbàgbọ́ wí pé Ó dára, wí pé Ó tóbi ju èyíkéyìí àwọn ìjàkadì wa lọ. Bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí kí o sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ síí kọ́ bí a ṣe lè pàdé Rẹ̀, ohùn Rẹ̀, ìwàláàyè Rẹ̀ —kí o sì da ara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin tí ń ní ìrírí Rush |Ẹ̀mí Mímọ́ Ní Ayé Òde-Òní.

More

A dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Gather (Loop/Wire) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: https://rushpodcast.com