Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ
Àwọn nnkan tí ó ko lè yí padà ńkọ́?
A kò lè yí ọkàn ẹlòmíràn padà. A kò lè yí ohun tó ti kọjá padà. A lè má lèe ṣe àkóso àyídáyidà ayé wa tàbí kí á yí i padà. Ṣùgbọ́n, njẹ́ o gbàgbọ́ pé Ọlọ́run nínú òye Rẹ̀ ní ìdí pàtàkì tí ó fi fi ọ́ sínú ayé pẹ̀lú awọn ọ̀ràn, ìbáṣepọ̀ àti ipò rẹ? Njẹ́ Ó wa le máa lo àwọn nnkan tí kò sí ní ìkáwọ́ wa láti kọ́ wa kí á fi ọkàn tán òhun fún ètò ayé wa tí kò ní yẹ̀? Ọlọ́run kìí fi ohunkóhun ṣòfò. Kìí fi ọkàn tí a sé le, àyídáyidà tí ó le, tàbí ohun tí kò sí ní ipá wa ṣofò. Kínni Ó lè máa fi hàn ọ́ nípa ayé rẹ tí o kò fẹ́ràn, ṣùgbọ́n tí o kò lè yí padà?
Ìbéèrè míràn tí kí á bi ara wa: ṣé à ń farada nnkan tí a kò lè yí padà ni tàbí a kàn ń gbàámọ́ra ni?
Ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàrin fífaradà àti gbígbàmọ́ra, ìyàtọ̀ ọ̀hún sì ni ìhùwàsí wa. Fífaradà túmọ̀ sí kí á ṣe ìwọ̀nba tó bá ṣeé ṣe láti tẹ̀ síwájú nígbà tí gbígbàmọ́ra ń gbé wa kọjáa kí á kàn wà láyé, sí kí á ṣe rere láàrin ìnira wa.
Nígbà tí a bá pinnu láti gba àgbàmọ́ra, nnkan lè má yí padà lójú wa, ṣùgbọ́n ìyípadà máa wà nínú ọkàn wa. Ó lè lo àwọn àyídáyidà tó kọ̀ láti yípadà láti se ọkàn wa, èyí tí kò bá má yípadà tẹ́lẹ́ rọ̀.
Orin Dafidi 37:4 lè fún wa ní òye to kún síi lórí ọ̀rọ̀ yìí." Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn nínú Olúwa, yó sì fún ọ́ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́." Nígbà tí mò ń dàgbà, èrò mi ni pé tí mo bá ṣe gbogbo ohun tí ó tọ́, màá rí gbogbo nnkan tí mo fẹ́ gbà... ìgbà tó pẹ́ ni ìtumọ̀ "dunnú" ṣẹ̀ṣẹ̀ yé mi. Nínú èdè Hébérù, "dunnú" túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹlẹgẹ́. Èyí tó túmọ̀ sí nnkan tí ó ṣeé yí padà àti nnkan tó rọ̀. Nígbà tí Ọlọ́run bá ní kí á dunnú si Òhun, nnkan tí Ó ń sọ ni pé, "Jẹ́ kí n tún ìwọ àti àwọn àníyàn rẹ mọ Bí o ti ń yọ̀ nínú Mi, àníyàn rẹ yóò di tèmi. Ohun tí mo fẹ́ ni ìwọ náà yóò fẹ́."
Njẹ́ Ó ńbi ọ́ pé kí o mòòkùn nínú àwọn ohun tí Ó ti fún ọ kí àwọn nnkan tí o kò lè yípadà lè di àwọn nnkan tí yóò yí ọ padà?
Olúwa, àwọn nnkan kan wà nínú ayé mi tí n kò fẹ́ràn, ṣùgbọ́n n kò ní agbára láti yí wọn padà. Fi hàn mí ohun tí mo lè ṣe láti yí ìhùwàsí àti ìrònú mi pádà. Mo fẹ́ ọkàn ẹran ara tí a fi ọwọ́ ìfẹ́ Rẹ mọ. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọ bí ohun tí mo ń là kọjá kò tilẹ̀ yé mi. Mo fi ipò tí ó ṣòro, tí ó sì kọ̀ láti yípadà yìí lé Ọ lọ́wọ́, mo sì bèèrè pé kí ìfẹ́ Rẹ kí ó ṣẹ.
Gbèrò láti ka àwọn ibi ìwé mímọ́ yìí nínú ẹ̀dà Bíbélì Message
Nípa Ìpèsè yìí
Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ
More