Bò Nínú Àjàgà Ìfarawéra Ẹ̀kọ́-Àṣàrò Ọlọ́jọ́ Méje Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ
Lọ́pọ̀ ìgbà ni a má nfi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn, aá sì pinnu pé a dára jù wọ́n lọ, a ṣe dáadáa jù wọ́n lọ, l'ẹ́wà, tírín, ní owo, ní àwọn ọ̀mọlẹ́yìn, ní ipa nlá jù wọ́n lọ. Nígbà náà, a ní ìmọ̀lára ipò gíga.
Ìṣòro tó pẹ̀lú èyí ni wípé ìmọ̀lára ipò gíga yí ní gbòngbò rẹ̀ nínú ìgbéraga. A sì mọ̀ láti inú Bíbélì ohún tí ó bá ìgbéraga rin. Ìṣubú.
Ìṣòro tí ó wà ninú ìfarawéra láti lérò pé ìwọ́ ló ga jù lọ ni wípé ẹlòmíràn yóò wà síwájú síi nígbà gbógbó, ẹlòmíràn á ṣe dáadáa jùlọ, á l'ẹ́wà jùlọ, pẹ̀lú ilé nlá, owo púpọ̀, àwọn ọmọlẹyìn díẹ̀ síi, àti ipa díẹ̀ síi jù wá lọ. Ìdí nìyí tí àbájáde kejì ìfarawéra jẹ́ ìparun sí ọkàn wa.
Nígbà tí a bá fi ara wa wé ẹlòmíràn, tí ó sì dà bíi wípé ó kù díẹ̀ kátò, a ní ìmọ̀lára wípé a ò t'ẹ́gbẹ́. Èyí sì ní ìfìdìmúlẹ̀ èrò àìlábò. Èyí ti kọjá àyè ìrẹ̀lẹ̀ bọ́ sínú èrò, ọkàn, àti ìhùwàsí búburú. Éró wípé a kù díẹ̀ lè já sí ìrẹ̀wẹ̀sì, ìbànújẹ́ ọkàn àti ẹ̀rù. Ìwà yìí yóò sì di pàkúté fún wa bákan náà nítorí pé á tì wá sínú túbú irọ́.
Rántí pé ìrẹ̀lẹ̀ òtítọ́ ni ohun tí à ńlépa nítorí ìrẹ̀lẹ̀ òtítọ́ ńmú inú Ọlọ́run dùn, ó sì n mú ògo Rẹ̀ yọ́. Fojú inú wòó bí ìwọ̀n tí ó pé. Ìrẹ̀lẹ̀ òtítọ mú wa dúró ṣinṣin, láì tẹ̀ sí apá kan ju òmíràn lọ.
Láti ní ìrẹ̀lẹ̀ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ lo ọpágun Rẹ̀ nìkan bíi igi òdiwọ̀n wa — gbogbo wa ní a sì mọ̀ bí a ti ṣe rí níwájú-u Rẹ̀.
Romu 3:23 sọ fún wa wípé “Nítorí gbogbo ènìyàn ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run.”
A kò jẹ́ nkankan níwájú Rẹ̀! Èyí ni ibi tí ìrẹ̀lẹ̀ — ìrẹ̀lẹ̀ tòótọ́ — ti wá, nítorí a kùnà, a kò sì lè ṣe é fúnra wa.
Fi ìgbésí ayé rẹ wé ọfà. Tafàtafà náà fà ọrùn sẹ̀hin, ó sì tú u sílẹ̀ sí ibi àfojúsùn. Àfojúsùn náà ni ìlànà Ọlọ́run fún ìgbésí ayé wa. Ọfà ná fò nnú afẹ́fẹ́ ṣùgbọ́n ó yára ṣubú ní kètè ti ibi-àfẹ́dé, kò kan ibi àfojúsùn náà rárá. Ohún tí Bíbélì túmọ̀ sí nìyí nígbà tí ó sọ pé a kùnà.
Ìhìnrere nà ni pé, Ọlọ́run nínú ìfẹ oún ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ fún wa ní Jésù, Ẹni tí ó mú ọfà wa tí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti rin ọ̀nà ìyókù. Nípasẹ̀ Jésù, a lè rìn ìrìn-àjò náà, ṣùgbọ́n a nílò RẸ̀! Gbogbo wá nílò Rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó dára jù lọ. Kò sí eni tí ó burú jù lọ. Ní ti iye wa, Ó rí gbogbo wa bákan náà. Nínú Rẹ̀ ni a ti ní ìdánimọ̀ wa tòótọ, nígbàtí a bá sì mọ ẹni tí a jẹ́, à ó rí ọ̀nà àti àníyàn wa, ìgbésí ayé tí Ó fi fún wa láti dìrò mọ́.
Ìrẹ̀lẹ̀ tòótọ́ tí ó sì wà fún ìgbà pipẹ́ yíó wá nígbà tí a bá tẹjú mọ́ ibi àfojusun wa, kìí ṣe tí àwọn ọfà yókù.
Olúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ojú mi lé Ọ, kí n má gbe lórí ohún tí àwọn ẹlòmíràn n ṣe tàbí tí wọ́n n sọ. Iye mi, ìdánimọ̀ àti ìtọ́sọ́nà wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan. Mo nfẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ òtítọ́ àti ọkàn tí ó wù Ọ́, tí ó sì bu ọlá fún Ọ. Fi àwọn agbègbè ìgbésí ayé mi hàn, ibi tí mo tẹ̀ sí ìgbéraga tàbí èrò àìláàbò, kí o sì mú mi padà sí ìbámu pẹ̀lú Rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìwọ́ mọ̀ wípé Ọlọ́rùn pèsè ìgbé ayé ọpọ yantúrú jú èyí tó ń gbé yì lọ, àmọ́ òtítọ́ tó kóro ní wípé ṣíṣe ìfáráwéra fà ọ sẹ́yìn láti lọ sí ipélé tó kan. Nínú ètò kíkà yìí Anna Light hú àwọn ìjìnlẹ̀ òye jáde láti fọ́ àpótí tí ìfáráwéra fi dé àwọ́n àbùdá rẹ, àti ràn ọ lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé òmìnira oún ìgbé ayé ọ́pọ yantúrú tí Ọlọ́rùn tí yà sọ́tọ fún ọ
More