O. Sol 4:9-10
O. Sol 4:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ ti gbà mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo! iwọ ti fi ọkan ninu ìwo oju rẹ, ati ọkan ninu ẹwọ̀n ọrùn rẹ gbà mi li ọkàn. Ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo! ifẹ rẹ ti sàn jù ọti-waini to! õrùn ikunra rẹ si jù turari gbogbo lọ.

O. Sol 4:9-10 Yoruba Bible (YCE)
O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi, ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí, pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ, ni o ti kó sí mi lórí. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi, ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ. Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ.
O. Sol 4:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ, Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!