O. Sol 4

4
1WÒ o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi: wò o, iwọ li ẹwà; iwọ li oju àdaba labẹ iboju rẹ: irun rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ, ti o dubulẹ lori òke Gileadi.
2Ehin rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ ti a rẹ́ ni irun, ti o gòke lati ibi iwẹ̀ wá, olukulùku wọn bi èjirẹ, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn.
3Ete rẹ dabi owu òdodo, ohùn rẹ si dùn: ẹ̀rẹkẹ rẹ si dabi ẹlà pomegranate kan labẹ iboju rẹ.
4Ọrùn rẹ dabi ile-iṣọ Dafidi ti a kọ́ fun ihamọra, lori eyi ti a fi ẹgbẹrun apata kọ́, gbogbo wọn jẹ asà awọn alagbara.
5Ọmu rẹ mejeji dabi abo egbin kekere meji ti iṣe èjirẹ, ti njẹ lãrin itanna lili.
6Titi ọjọ yio fi rọ̀, ti ojiji yio si fi fò lọ, emi o lọ si òke nla ojia, ati si òke kékeké turari.
7Iwọ li ẹwà gbogbo, olufẹ mi; kò si abawọ́n lara rẹ!
8Ki a lọ kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lọ kuro ni Lebanoni: wò lati ori òke Amana, lati ori òke Ṣeniri ati Hermoni, lati ibi ihò kiniun, lati òke awọn ẹkùn.
9Iwọ ti gbà mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo! iwọ ti fi ọkan ninu ìwo oju rẹ, ati ọkan ninu ẹwọ̀n ọrùn rẹ gbà mi li ọkàn.
10Ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo! ifẹ rẹ ti sàn jù ọti-waini to! õrùn ikunra rẹ si jù turari gbogbo lọ.
11Iyawo! ète rẹ nkán bi afara-oyin: oyin ati wàra mbẹ labẹ ahọn rẹ; õrun aṣọ rẹ si dabi õrun Lebanoni.
12Ọgbà ti a sọ ni arabinrin mi, iyawo! isun ti a sé, orisun ti a fi edidi dí.
13Ohun gbigbìn rẹ agbala pomegranate ni, ti on ti eso ti o wunni; kipressi ati nardi.
14Nardi ati saffroni; kalamusi, kinnamoni, pẹlu gbogbo igi turari; ojia ati aloe, pẹlu gbogbo awọn olori olõrun didùn.
15Orisun ninu ọgba kanga omi iyè, ti nṣan lati Lebanoni wá.
16Ji afẹfẹ ariwa; si wá, iwọ ti gusu; fẹ́ sori ọgbà mi, ki õrun inu rẹ̀ le fẹ́ jade. Jẹ ki olufẹ mi wá sinu ọgbà rẹ̀, ki o si jẹ eso didara rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Sol 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa