O. Sol 4:1-9

O. Sol 4:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi, ẹwà rẹ pọ̀. Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ, irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn, tí wọn wá fọ̀; gbogbo wọn gún régé, Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn. Ètè rẹ dàbí òwú pupa; ẹnu rẹ fanimọ́ra, ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate, lábẹ́ ìbòjú rẹ. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ fún ihamọra, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́, bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì, tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. N óo wà lórí òkè òjíá, ati lórí òkè turari, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, tí òkùnkùn yóo sì lọ. O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi! O dára dára, o ò kù síbìkan, kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ. Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi, máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni. Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana, kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni, kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé. O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi, ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí, pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ, ni o ti kó sí mi lórí.

O. Sol 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi! Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà! Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi. Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró. Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó; ẹnu rẹ̀ dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára. Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì. Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí. Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ. Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ