O. Sol 3:1-4
O. Sol 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI oru lori akete mi, mo wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i. Emi o dide nisisiyi, emi o si rìn lọ ni ilu, ni igboro, ati li ọ̀na gbòro ni emi o wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i. Awọn oluṣọ ti nrìn ilu yika ri mi: mo bère pe, Ẹ ha ri ẹniti ọkàn mi fẹ bi? Ṣugbọn bi mo ti fi wọn silẹ gẹrẹ ni mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: mo dì i mu, emi kò si jọ̃rẹ̀ lọwọ, titi mo fi mu u wá sinu ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o loyun mi.
O. Sol 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́, lórí ibùsùn mi lálẹ́, mo wá a, ṣugbọn n kò rí i; mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú, n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́, ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede. Mo wá a ṣugbọn n kò rí i. Àwọn aṣọ́de rí mi, bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú. Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ, títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi, ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.
O. Sol 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní orí ibùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i. Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde; Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i. Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú. “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi