Ní orí ibùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i. Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú, ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde; Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i. Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú. “Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi, sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi
Kà Orin Solomoni 3
Feti si Orin Solomoni 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Orin Solomoni 3:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò