O. Daf 99:1-9
O. Daf 99:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA jọba; jẹ ki awọn enia ki o wariri: o joko lori awọn kerubu; ki aiye ki o ta gbọ̀ngbọ́n. Oluwa tobi ni Sioni: o si ga jù gbogbo orilẹ-ède lọ. Ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru; mimọ́ li on. Agbara ọba fẹ idajọ pẹlu, iwọ fi idi aiṣegbe mulẹ; iwọ nṣe idajọ ati ododo ni Jakobu. Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ̀: mimọ́ li on. Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ̀, ati Samueli ninu awọn ti npè orukọ rẹ̀: nwọn ke pè Oluwa, o si da wọn lohùn. O ba wọn sọ̀rọ ninu ọwọ̀n awọsanma: nwọn pa ẹri rẹ̀ mọ́ ati ilana ti o fi fun wọn. Iwọ da wọn lohùn, Oluwa Ọlọrun wa: iwọ li Ọlọrun ti o dariji wọn, ti o si san ẹsan iṣẹ wọn. Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sìn nibi òke mimọ́ rẹ̀; nitori Oluwa Ọlọrun wa mimọ́ ni.
O. Daf 99:1-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì; ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì. OLUWA tóbi ní Sioni, ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, mímọ́ ni OLUWA! Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo, o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀; o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀; mímọ́ ni OLUWA! Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀; Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀; wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu; wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́; wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn. OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn; Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn; ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀; nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.
O. Daf 99:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA jẹ ọba; jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì. OLúWA tóbi ní Sioni; Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ. Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun. Ọba ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo, ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀; ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu. Gbígbéga ni OLúWA Ọlọ́run wa ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́. Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀ Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀ wọ́n ké pe OLúWA, ó sì dá wọn lóhùn. Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀, wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn. OLúWA Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn; ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n Gbígbéga ni OLúWA Ọlọ́run wa kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀ nítorí OLúWA Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.