OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì; ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì. OLUWA tóbi ní Sioni, ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, mímọ́ ni OLUWA! Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo, o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀; o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀; mímọ́ ni OLUWA! Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀; Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀; wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu; wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́; wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn. OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn; Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn; ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀; nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.
Kà ORIN DAFIDI 99
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 99:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò