O. Daf 98:7-9
O. Daf 98:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀. Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀. Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.

O. Daf 98:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́; kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀ níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.
O. Daf 98:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀; Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú OLúWA Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.