Saamu 98

98
Saamu 98
1Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀
o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un
2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀
o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.
3Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;
gbogbo òpin ayé ni ó ti rí
iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.
4Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,
ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn
5Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6Pẹ̀lú ìpè àti fèrè
ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
7Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo
ohun tí ó wà nínú rẹ̀,
Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,
ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa
Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo
àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Saamu 98: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀