O. Daf 92:1-15

O. Daf 92:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA; kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo; ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀, kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́, pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá, ati hapu. Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ; OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA! Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ! Òpè eniyan kò lè mọ̀, kò sì le yé òmùgọ̀: pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko, tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀, ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn. Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA. Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun; gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká. Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n; o ti da òróró dáradára sí mi lórí. Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi, mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí. Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ, wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni. Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA, tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa. Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn, wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo; láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA; òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀.

O. Daf 92:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún OLúWA àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo, Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́ Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá àti lára ohun èlò orin haapu. Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ OLúWA; èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, OLúWA? Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni! Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n, aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n, Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú, wọn yóò run láéláé. Ṣùgbọ́n ìwọ OLúWA ni a ó gbéga títí láé. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, OLúWA, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká. Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí. Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi. Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni; Tí a gbìn sí ilé OLúWA, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa. Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó, wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini, Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni OLúWA; òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú kankan nínú rẹ̀.”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa