OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo: Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ. Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu. Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ. Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi. Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia. Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni: Ṣugbọn iwọ, Oluwa li ẹniti o ga titi lai. Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka. Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori. Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi. Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni. Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa. Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini; Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.
Kà O. Daf 92
Feti si O. Daf 92
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 92:1-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò