O. Daf 89:15-18
O. Daf 89:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ. Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke. Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke, Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa.
O. Daf 89:15-18 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì, àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA, àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru, tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn; nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun. Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa; ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.
O. Daf 89:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì, OLúWA wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo rẹ. Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn; nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo. Nítorí ti OLúWA ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.