ORIN DAFIDI 89:15-18

ORIN DAFIDI 89:15-18 YCE

Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì, àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA, àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru, tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn; nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun. Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa; ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.