O. Daf 86:11-17
O. Daf 86:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLúWA, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ. Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú. Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run; àti ìjọ àwọn alágbára ń wá ọkàn mi kiri, wọn kò sì fi ọ́ pè. Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́. Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi; fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là. Fi ààmì hàn mí fún rere, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri, kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ OLúWA ni ó ti tù mí nínú.
O. Daf 86:11-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o ma rìn ninu otitọ rẹ: mu aiya mi ṣọkan lati bẹ̀ru orukọ rẹ. Emi o yìn ọ, Oluwa Ọlọrun mi, tinutinu mi gbogbo: emi o si ma fi ogo fun orukọ rẹ titi lai. Nitoripe nla li ãnu rẹ si mi: iwọ si ti gbà ọkàn mi lọwọ isa-okú jijin. Ọlọrun, awọn agberaga dide si mi, ati ijọ awọn alagbara nwá ọkàn mi kiri; nwọn kò si fi ọ pè li oju wọn. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ. Yipada si mi ki o si ṣãnu fun mi; fi ipá rẹ fun iranṣẹ rẹ, ki o si gbà ọmọkunrin iranṣẹ-birin rẹ là. Fi àmi hàn mi fun rere; ki awọn ti o korira mi ki o le ri i, ki oju ki o le tì wọn, nitori iwọ, Oluwa, li o ti ràn mi lọwọ ti o si tù mi ninu.
O. Daf 86:11-17 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ; kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi; n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi; o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú. Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi; ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò sì bìkítà fún ọ. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore; o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi; fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ; kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là. Fi àmì ojurere rẹ hàn mí, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n; nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́, tí o sì tù mí ninu.