O. Daf 86:1-7
O. Daf 86:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini. Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ. Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ. Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ. Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi. Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn.
O. Daf 86:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi, nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí. Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí; gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là; ìwọ ni Ọlọrun mi. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru. Mú inú iranṣẹ rẹ dùn, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. Fetí sí adura mi, OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́, nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.
O. Daf 86:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́, OLúWA, kí o sì dá mi lóhùn, nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní. Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ: ìwọ ni Ọlọ́run mi, gbà ìránṣẹ́ rẹ là tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. Ṣàánú fún mi, OLúWA, nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́. Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ, OLúWA, ni mo gbé ọkàn mí sókè sí. Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, OLúWA, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́, Gbọ́ àdúrà mi, OLúWA; tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.