O. Daf 73:1-17

O. Daf 73:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli, ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́. Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé. Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Wọn kì í jẹ ìrora kankan, ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀. Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn; ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà, wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ. Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò; èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara; wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun; wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé. Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn, wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe. Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀? Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?” Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí; ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i. Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́, tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu; láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,” n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi, mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ, ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

O. Daf 73:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán. Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú. Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára. Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn. Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ. Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga. Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run ahọ́n wọn gba ipò ayé. Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀? Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?” Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀. Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀. Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀. Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi. Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.