ORIN DAFIDI 73:1-17

ORIN DAFIDI 73:1-17 YCE

Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli, ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́. Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé. Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Wọn kì í jẹ ìrora kankan, ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀. Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn; ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà, wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ. Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò; èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara; wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun; wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé. Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn, wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe. Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀? Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?” Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí; ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i. Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́, tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu; láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,” n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi, mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ, ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.