O. Daf 68:1-18

O. Daf 68:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká. Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀. Bí èéfín tií pòórá, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́; bí ìda tií yọ́ níwájú iná, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun. Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn, kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun; kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀, ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin. OLUWA ni orúkọ rẹ̀; ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀. Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun, ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà; ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra, ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ, nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò, níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai, àní, níwájú Ọlọrun Israẹli. Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀; o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò. Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀; Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní. OLUWA fọhùn, ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn; àwọn obinrin tí ó wà nílé, ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín: fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà; wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká, ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́. Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá; Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ. Ẹ̀yin òkè olórí pupọ, kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé, ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae? OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀ pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun, ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun. Ó gun òkè gíga, ó kó àwọn eniyan nígbèkùn; ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan, ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá. OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.

O. Daf 68:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká; kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀. Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ, kí ó fẹ́ wọn lọ; bí ìda ti í yọ́ níwájú iná, kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run; kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀. Ẹ kọrin sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn sí i, ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù. OLúWA ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀. Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́ Ọlọ́run gbé aláìlera kalẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run, tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela. Ilẹ̀ mì títí, àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde, níwájú Ọlọ́run, ẹni Sinai, níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli. Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run; ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan. Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní. Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀. “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ; Obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà. Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran, nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà, àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.” Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà, ó dàbí òjò dídi ní Salmoni. Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run; òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani. Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara, ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé? Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀. Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ; ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn: nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, Kí OLúWA Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

O. Daf 68:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

KI Ọlọrun ki o dide, ki a si tú awọn ọta rẹ̀ ka: ki awọn ti o korira rẹ̀ pẹlu, ki nwọn ki o salọ kuro niwaju rẹ̀. Bi ẽfin ti ifẹ lọ, bẹ̃ni ki o fẹ́ wọn lọ; bi ida ti iyọ́ niwaju iná, bẹ̃ni ki enia buburu ki o ṣegbe niwaju Ọlọrun. Ṣugbọn jẹ ki inu awọn olododo ki o dùn; ki nwọn ki o yọ̀ niwaju Ọlọrun; nitõtọ, ki nwọn ki o yọ̀ gidigidi. Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹ kọrin iyin si orukọ rẹ̀: ẹ la ọ̀na fun ẹniti nrekọja li aginju nipa JAH, orukọ rẹ̀, ki ẹ si ma yọ̀ niwaju rẹ̀. Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́. Ọlọrun mu ẹni-ofo joko ninu ile: o mu awọn ti a dè li ẹ̀wọn jade wá si irọra: ṣugbọn awọn ọlọtẹ ni ngbe inu ilẹ gbigbẹ. Ọlọrun, nigbati iwọ jade lọ niwaju awọn enia rẹ, nigbati iwọ nrìn lọ larin aginju. Ilẹ mì, ọrun bọ silẹ niwaju Ọlọrun: ani Sinai tikararẹ̀ mì niwaju Ọlọrun, Ọlọrun Israeli. Ọlọrun, iwọ li o rán ọ̀pọlọpọ òjo si ilẹ-ini rẹ, nigbati o rẹ̀ ẹ tan, iwọ tù u lara. Ijọ enia rẹ li o tẹ̀do sinu rẹ̀: iwọ Ọlọrun ninu ore rẹ li o ti pèse fun awọn talaka. Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀: Awọn ọba awọn ẹgbẹ ogun sa, nwọn sa lọ: obinrin ti o si joko ni ile ni npin ikogun na. Nigbati ẹnyin dubulẹ larin agbo ẹran, nigbana ni ẹnyin o dabi iyẹ adaba ti a bò ni fadaka, ati ìyẹ́ rẹ̀ pẹlu wura pupa. Nigbati Olodumare tú awọn ọba ká ninu rẹ̀, o dabi òjo-didì ni Salmoni. Òke Ọlọrun li òke Baṣani: òke ti o ni ori pupọ li òke Baṣani. Ẽṣe ti ẹnyin nfi ilara wò, ẹnyin òke, òke na ti Ọlọrun fẹ lati ma gbe? nitõtọ, Oluwa yio ma gbe ibẹ lailai. Ainiye ni kẹkẹ́ ogun Ọlọrun, ani ẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun: Oluwa mbẹ larin wọn, ni Sinai ni ibi mimọ́ nì. Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.